O. Daf 93 - Bibeli MimọỌlọrun Ọba 1 OLUWA jọba, ọla-nla li o wọ li aṣọ; agbara ni Oluwa wọ̀ li aṣọ, o fi di ara rẹ̀ li amure: o si fi idi aiye mulẹ, ti kì yio fi le yi. 2 Lati igba atijọ li a ti fi idi itẹ́ rẹ kalẹ, ati aiye-raiye ni Iwọ. 3 Iṣan-omi gbé ohùn wọn soke, Oluwa, iṣan-omi gbé ohùn wọn soke; iṣan-omi gbé riru omi wọn soke. 4 Oluwa li ologo, o li ogo jù ariwo omi pupọ lọ, jù riru omi nla, ani jù agbara riru omi okun lọ. 5 Otitọ li ẹri rẹ: ìwa-mimọ́ li o yẹ ile rẹ lailai, Oluwa. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria