O. Daf 92 - Bibeli MimọOrin Ìyìn Orin fun ọjọ isimi. 1 OHUN rere ni lati ma fi ọpẹ fun Oluwa, ati lati ma kọrin si orukọ rẹ, Ọga-ogo: 2 Lati ma fi iṣeun ifẹ rẹ hàn li owurọ, ati otitọ rẹ li alalẹ. 3 Lara ohun-elo orin olokùn mẹwa, ati lara ohun-elo orin mimọ́: lara duru pẹlu iró ti o ni ironu. 4 Nitori iwọ, Oluwa, li o ti mu mi yọ̀ nipa iṣẹ rẹ: emi o ma kọrin iyìn nitori iṣẹ ọwọ rẹ. 5 Oluwa, iṣẹ rẹ ti tobi to! ìro-inu rẹ jinlẹ gidigidi. 6 Ope enia kò mọ̀; bẹ̃li oye eyi kò ye aṣiwere enia. 7 Nigbati awọn enia buburu ba rú bi koriko, ati igbati gbogbo awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ ba ngberú: ki nwọn ki o le run lailai ni: 8 Ṣugbọn iwọ, Oluwa li ẹniti o ga titi lai. 9 Sa wò o, awọn ọta rẹ, Oluwa, sa wò o, awọn ọta rẹ yio ṣegbe; gbogbo oniṣẹ ẹ̀ṣẹ li a o tuka. 10 Ṣugbọn iwo mi ni iwọ o gbé ga bi iwo agbanrere; ororo titun li a o ta si mi lori. 11 Oju mi pẹlu yio ri ifẹ mi lara awọn ọta mi, eti mi yio si ma gbọ́ ifẹ mi si awọn enia buburu ti o dide si mi. 12 Olododo yio gbà bi igi ọpẹ: yio dàgba bi igi kedari Lebanoni. 13 Awọn ẹniti a gbin ni ile Oluwa, yio gbà ni agbala Ọlọrun wa. 14 Nwọn o ma so eso sibẹ ninu ogbó wọn: nwọn o sanra, nwọn o ma tutù nini; 15 Lati fi hàn pe, Ẹni diduro-ṣinṣin ni Oluwa: on li apata mi, kò si si aiṣododo kan ninu rẹ̀. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria