O. Daf 86 - Bibeli MimọAdura Ìrànlọ́wọ́ 1 OLUWA, dẹ eti rẹ silẹ, gbohùn mi: nitori ti emi jẹ́ talaka ati alaini. 2 Pa ọkàn mi mọ́; nitori emi li ẹniti iwọ ṣe ojurere fun: iwọ, Ọlọrun mi, gbà ọmọ ọdọ rẹ ti o gbẹkẹle ọ. 3 Ṣãnu fun mi, Oluwa: nitori iwọ li emi nkepè lojojumọ. 4 Mu ọkàn iranṣẹ rẹ yọ̀: Oluwa, nitori iwọ ni mo gbé ọkàn mi soke si. 5 Nitori iwọ, Oluwa, o ṣeun, o si mura ati dariji; o si pọ̀ li ãnu fun gbogbo awọn ti nkepè ọ. 6 Oluwa, fi eti si adura mi; ki o si fiye si ohùn ẹ̀bẹ mi. 7 Li ọjọ ipọnju mi, emi o kepè ọ: nitori ti iwọ o da mi lohùn. 8 Oluwa, ninu awọn oriṣa kò si ọ̀kan ti o dabi rẹ, bẹ̃ni kò si iṣẹ kan ti o dabi iṣẹ rẹ. 9 Gbogbo awọn orilẹ-ède ti iwọ da ni yio wá, nwọn o si sìn niwaju rẹ, Oluwa; nwọn o si ma fi ogo fun orukọ rẹ. 10 Nitoripe iwọ pọ̀, iwọ si nṣe ohun iyanu: iwọ nikan li Ọlọrun. 11 Oluwa, kọ́ mi li ọ̀na rẹ; emi o ma rìn ninu otitọ rẹ: mu aiya mi ṣọkan lati bẹ̀ru orukọ rẹ. 12 Emi o yìn ọ, Oluwa Ọlọrun mi, tinutinu mi gbogbo: emi o si ma fi ogo fun orukọ rẹ titi lai. 13 Nitoripe nla li ãnu rẹ si mi: iwọ si ti gbà ọkàn mi lọwọ isa-okú jijin. 14 Ọlọrun, awọn agberaga dide si mi, ati ijọ awọn alagbara nwá ọkàn mi kiri; nwọn kò si fi ọ pè li oju wọn. 15 Ṣugbọn iwọ, Oluwa, li Ọlọrun ti o kún fun iyọ́nu, ati olore-ọfẹ, olupamọra, o si pọ̀ li ãnu ati otitọ. 16 Yipada si mi ki o si ṣãnu fun mi; fi ipá rẹ fun iranṣẹ rẹ, ki o si gbà ọmọkunrin iranṣẹ-birin rẹ là. 17 Fi àmi hàn mi fun rere; ki awọn ti o korira mi ki o le ri i, ki oju ki o le tì wọn, nitori iwọ, Oluwa, li o ti ràn mi lọwọ ti o si tù mi ninu. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria