O. Daf 85 - Bibeli MimọAdura Ire Orílẹ̀-Èdè 1 OLUWA, iwọ ti nṣe oju rere si ilẹ rẹ: iwọ ti mu igbekun Jakobu pada bọ̀. 2 Iwọ ti dari aiṣedede awọn enia rẹ jì, iwọ ti bò gbogbo ẹ̀ṣẹ wọn mọlẹ. 3 Iwọ ti mu gbogbo ibinu rẹ kuro: iwọ ti yipada kuro ninu gbigbona ibinu rẹ. 4 Yi wa pada, Ọlọrun igbala wa, ki o si mu ibinu rẹ si wa ki o dá. 5 Iwọ o binu si wa titi lai? iwọ o fà ibinu rẹ jade lati irandiran? 6 Iwọ kì yio tun mu wa sọji: ki awọn enia rẹ ki o ma yọ̀ ninu rẹ? 7 Oluwa fi ãnu rẹ hàn fun wa, ki o si fun wa ni igbala rẹ. 8 Emi o gbọ́ bi Ọlọrun Oluwa yio ti wi: nitoriti yio sọ alafia si awọn enia rẹ̀, ati si awọn enia mimọ́ rẹ̀: ṣugbọn ki nwọn ki o má tun pada si were. 9 Nitõtọ igbala rẹ̀ sunmọ́ awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀; ki ogo ki o le ma gbé ilẹ wa. 10 Ãnu ati otitọ padera; ododo ati alafia ti fi ẹnu kò ara wọn li ẹnu. 11 Otitọ yio rú jade lati ilẹ wá: ododo yio si bojuwò ilẹ lati ọrun wá. 12 Nitõtọ Oluwa yio funni li eyi ti o dara; ilẹ wa yio si ma mu asunkun rẹ̀ wá. 13 Ododo yio ṣãju rẹ̀; yio si fi ipasẹ rẹ̀ ṣe ọ̀na. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria