O. Daf 83 - Bibeli MimọAdura Ìṣẹ́gun 1 MAṢE dakẹ, Ọlọrun: máṣe pa ẹnu rẹ mọ́, ki o má si ṣe duro jẹ, Ọlọrun. 2 Sa wò o, awọn ọta rẹ nrọkẹ̀kẹ: awọn ti o korira rẹ ti gbé ori soke. 3 Nwọn ti gbimọ̀ arekereke si awọn enia rẹ, nwọn si ti gbèro si awọn ẹni-ìkọ̀kọ̀ rẹ. 4 Nwọn ti wipe, Ẹ wá, ẹ jẹ ki a ke wọn kuro lati má wà li orilẹ-ède; ki orukọ Israeli ki o máṣe si ni iranti mọ́. 5 Nitoriti nwọn ti gbimọ̀ pọ̀ ṣọkan: nwọn ti dimọlu si ọ. 6 Agọ Edomu, ati ti awọn ọmọ Iṣmaeli; ti Moabu, ati awọn ọmọ Hagari. 7 Gebali, ati Ammoni, ati Amaleki: awọn ara Filistia pẹlu awọn ara Tire; 8 Assuri pẹlu dapọ̀ mọ wọn: nwọn ràn awọn ọmọ Loti lọwọ. 9 Ṣe wọn bi o ti ṣe awọn ara Midiani; bi Sisera, bi Jabini, li odò Kiṣoni. 10 Ẹniti o ṣegbe ni Endori: nwọn di àtan fun ilẹ. 11 Ṣe awọn ọlọla wọn bi Orebu ati bi Sebu: ani, gbogbo awọn ọmọ-alade wọn bi Seba ati Salmuna. 12 Awọn ti o wipe, Ẹ jẹ ki a gbà ibugbe Ọlọrun wọnni fun ara wa ni ini. 13 Ọlọrun mi, ṣe wọn bi ãjà; bi akeku koriko niwaju afẹfẹ. 14 Bi iná ti ijo igbo, ati bi ọwọ́ iná ti imu òke-nla gbiná; 15 Bẹ̃ni ki o fi ẹ̀fufu rẹ ṣe inunibini si wọn, ki o si fi ìji rẹ dẹrubà wọn. 16 Fi ìtiju kún wọn li oju: ki nwọn o le ma ṣe afẹri orukọ rẹ, Oluwa. 17 Ki nwọn ki o dãmu ki a si pọ́n wọn loju lailai; nitõtọ, ki a dojutì wọn, ki nwọn ki o ṣegbé. 18 Ki awọn enia ki o le mọ̀ pe iwọ, orukọ ẹni-kanṣoṣo ti ijẹ Jehofah, iwọ li Ọga-ogo lori aiye gbogbo. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria