O. Daf 8 - Bibeli MimọÒgo OLUWA ati ipò eniyan 1 OLUWA, Oluwa wa, orukọ rẹ ti ni iyìn to ni gbogbo aiye! iwọ ti o gbé ogo rẹ kà ori awọn ọrun. 2 Lati ẹnu awọn ọmọ-ọwọ ati ọmọ-ọmu ni iwọ ti ṣe ilana agbara, nitori awọn ọta rẹ, nitori ki iwọ ki o le mu ọta olugbẹsan nì dakẹjẹ. 3 Nigbati mo rò ọrun rẹ, iṣẹ ika rẹ, oṣupa ati irawọ, ti iwọ ti ṣe ilana silẹ. 4 Kili enia, ti iwọ fi nṣe iranti rẹ̀? ati ọmọ enia, ti iwọ fi mbẹ̀ ẹ wò. 5 Iwọ sa da a li onirẹlẹ diẹ jù Ọlọrun lọ, iwọ si ti fi ogo ati ọlá de e li ade. 6 Iwọ mu u jọba iṣẹ ọwọ rẹ; iwọ si ti fi ohun gbogbo sabẹ ẹsẹ rẹ̀; 7 Awọn agutan ati awọn malu pẹlu, ati awọn ẹranko igbẹ; 8 Awọn ẹiyẹ oju ọrun, ati awọn ẹja okun, ti o nkọja lọ nipa ọ̀na okun. 9 Oluwa, Oluwa wa, orukọ rẹ ti ni iyìn to ni gbogbo aiye! |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria