O. Daf 72 - Bibeli MimọAdura Ọba 1 ỌLỌRUN, fi idajọ rẹ fun ọba, ati ododo rẹ fun ọmọ ọba. 2 On o ma fi ododo ṣe idajọ awọn enia rẹ, yio si ma fi ẹtọ́ ṣe idajọ awọn talaka rẹ. 3 Awọn òke nla yio ma mu alafia fun awọn enia wá, ati awọn òke kekeke nipa ododo. 4 On o ma ṣe idajọ awọn talaka enia, yio ma gbà awọn ọmọ awọn alaini, yio si fà aninilara ya pẹrẹ-pẹrẹ. 5 Nwọn o si ma bẹ̀ru rẹ, niwọ̀n bi õrùn ati oṣupa yio ti pẹ to, lati irandiran. 6 On o rọ̀ si ilẹ bi ojò si ori koriko itẹ̀mọlẹ: bi ọwọ òjo ti o rin ilẹ. 7 Li ọjọ rẹ̀ li awọn olododo yio gbilẹ: ati ọ̀pọlopọ alafia niwọn bi òṣupa yio ti pẹ to. 8 On o si jọba lati okun de okun, ati lati odò nì de opin aiye. 9 Awọn ti o joko li aginju yio tẹriba fun u; awọn ọta rẹ̀ yio si lá erupẹ ilẹ. 10 Awọn ọba Tarṣiṣi, ati ti awọn erekuṣu yio mu ọrẹ wá: awọn ọba Ṣeba ati ti Seba yio mu ẹ̀bun wá. 11 Nitõtọ, gbogbo awọn ọba ni yio wolẹ niwaju rẹ̀: gbogbo awọn orilẹ-ède ni yio ma sìn i. 12 Nitori yio gbà alaini nigbati o ba nke: talaka pẹlu, ati ẹniti kò li oluranlọwọ. 13 On o da talaka ati alaini si, yio si gbà ọkàn awọn alaini là. 14 On o rà ọkàn wọn pada lọwọ ẹ̀tan ati ìwa-agbara: iyebiye si li ẹ̀jẹ wọn li oju rẹ̀. 15 On o si yè, on li a o si fi wura Ṣeba fun: a o si ma gbadura fun u nigbagbogbo: lojojumọ li a o si ma yìn i. 16 Ikúnwọ ọkà ni yio ma wà lori ilẹ, lori awọn òke nla li eso rẹ̀ yio ma mì bi Lebanoni: ati awọn ti inu ilu yio si ma gbà bi koriko ilẹ. 17 Orukọ rẹ̀ yio wà titi lai: orukọ rẹ̀ yio ma gbilẹ niwọn bi õrun yio ti pẹ to: nwọn o si ma bukún fun ara wọn nipaṣẹ rẹ̀: gbogbo awọn orilẹ-ède ni yio ma pè e li alabukúnfun. 18 Olubukún li Oluwa Ọlọrun, Ọlọrun Israeli, ẹnikanṣoṣo ti nṣe ohun iyanu. 19 Olubukún li orukọ rẹ̀ ti o li ogo titi lai: ki gbogbo aiye ki o si kún fun ogo rẹ̀. Amin, Amin. 20 Adura Dafidi ọmọ Jesse pari. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria