O. Daf 64 - Bibeli MimọAdura Ààbò 1 ỌLỌRUN, gbohùn mi ninu aroye mi: pa ẹmi mi mọ́ lọwọ ẹ̀ru ọta nì. 2 Pa mi mọ́ lọwọ ìmọ ìkọkọ awọn enia buburu: lọwọ irukerudo awọn oniṣẹ-ẹ̀ṣẹ. 3 Ẹniti npọ̀n ahọn wọn bi ẹnipe idà, ti nwọn si fa ọrun wọn le lati tafa wọn, ani ọ̀rọ kikoro: 4 Ki nwọn ki o le ma tafà ni ìkọkọ si awọn ti o pé: lojiji ni nwọn tafa si i, nwọn kò si bẹ̀ru. 5 Nwọn gba ara wọn niyanju li ọ̀ran buburu: nwọn gbìmọ ati dẹkun silẹ nikọ̀kọ; nwọn wipe, Tani yio ri wọn? 6 Nwọn gbero ẹ̀ṣẹ; nwọn wipe, awa ti pari ero ti a gbà tan: ati ìro inu olukuluku wọn, ati aiya wọn, o jinlẹ. 7 Ṣugbọn Ọlọrun yio tafà si wọn lojiji; nwọn o si gbọgbẹ. 8 Bẹ̃ni ahọn wọn yio mu wọn ṣubu lu ara wọn: gbogbo ẹniti o ri wọn yio mì ori wọn. 9 Ati gbogbo enia ni yio ma bẹ̀ru, nwọn o si ma sọ̀rọ iṣẹ Ọlọrun; nitoriti nwọn o fi ọgbọ́n rò iṣẹ rẹ̀. 10 Olododo yio ma yọ̀ nipa ti Oluwa, yio si ma gbẹkẹle e; ati gbogbo ẹni-iduro-ṣinṣin li aiya ni yio ma ṣogo. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria