O. Daf 6 - Bibeli MimọAdura nígbà ìyọnu 1 OLUWA, máṣe ba mi wi ni ibinu rẹ, ki iwọ ki o má ṣe nà mi ni gbigbona ibinujẹ rẹ. 2 Oluwa, ṣãnu fun mi; nitori ailera mi: Oluwa, mu mi lara da; nitori ti ara kan egungun mi. 3 Ara kan ọkàn mi gogo pẹlu: ṣugbọn iwọ, Oluwa, yio ti pẹ to! 4 Pada, Oluwa, gbà ọkàn mi: gbà mi là nitori ãnu rẹ. 5 Nitoriti kò si iranti rẹ ninu okú: ninu isa okú tani yio dupẹ fun ọ? 6 Agara ikerora mi da mi: li oru gbogbo li emi nmu ẹní mi fó li oju omi; emi fi omije mi rin ibusùn mi. 7 Oju mi bajẹ tan nitori ibinujẹ; o di ogbó tan nitori gbogbo awọn ọta mi. 8 Ẹ lọ kuro lọdọ mi, gbogbo ẹnyin oniṣẹ ẹ̀ṣẹ; nitori ti Oluwa gbọ́ ohùn ẹkún mi. 9 Oluwa gbọ́ ẹ̀bẹ mi; Oluwa yio gbà adura mi. 10 Oju yio tì gbogbo awọn ọta mi, ara yio sì kan wọn gogo: nwọn o pada, oju yio tì wọn lojíji. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria