O. Daf 59 - Bibeli MimọAdura Ààbò Orin Dafidi, nigbati Saulu ranṣẹ, ti nwọn si nṣọ ile lati pa a. 1 ỌLỌRUN mi, gbà mi lọwọ awọn ọta mi: dãbobo mi lọwọ awọn ti o dide si mi. 2 Gbà mi lọwọ awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ, ki o si gbà mi silẹ lọwọ awọn enia-ẹ̀jẹ. 3 Sa kiyesi i, nwọn ba ni buba fun ọkàn mi, awọn alagbara pejọ si mi; kì iṣe nitori irekọja mi, tabi nitori ẹ̀ṣẹ mi, Oluwa. 4 Nwọn sure, nwọn mura li aiṣẹ mi: dide lati pade mi, ki o si kiyesi i. 5 Nitorina iwọ, Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, jí lati bẹ̀ gbogbo awọn keferi wò; máṣe ṣãnu fun olurekọja buburu wọnni. 6 Nwọn pada li aṣalẹ: nwọn npariwo bi ajá, nwọn nrìn yi ilu na ka. 7 Kiyesi i, nwọn nfi ẹnu wọn gùfẹ jade: idà wà li ète wọn: nitoriti nwọn nwipe, tali o gbọ́? 8 Ṣugbọn iwọ, Oluwa, yio rẹrin wọn: iwọ ni yio yọṣuti si gbogbo awọn keferi. 9 Agbara rẹ̀ li emi o duro tì: nitori Ọlọrun li àbo mi. 10 Ọlọrun ãnu mi ni yio ṣaju mi: Ọlọrun yio jẹ ki emi ri ifẹ mi lara awọn ọta mi. 11 Máṣe pa wọn, ki awọn enia mi ki o má ba gbagbe: tú wọn ká nipa agbara rẹ; ki o si sọ̀ wọn kalẹ, Oluwa asà wa. 12 Nitori ẹ̀ṣẹ ẹnu wọn ni ọ̀rọ ète wọn, ki a mu wọn ninu igberaga wọn: ati nitori ẽbu ati èke ti nwọn nṣe. 13 Run wọn ni ibinu, run wọn, ki nwọn ki o má ṣe si mọ́: ki o si jẹ ki nwọn ki o mọ̀ pe, Ọlọrun li olori ni Jakobu titi o fi de opin aiye. 14 Ati li aṣalẹ jẹ ki nwọn ki o pada; ki nwọn ki o pariwo bi ajá, ki nwọn ki o si ma yi ilu na ka kiri. 15 Jẹ ki nwọn ki o ma rìn soke rìn sodò fun ohun jijẹ, bi nwọn kò ba yó, nwọn o duro ni gbogbo oru na. 16 Ṣugbọn emi o kọrin agbara rẹ; nitõtọ, emi o kọrin ãnu rẹ kikan li owurọ: nitori pe iwọ li o ti nṣe àbo ati ibi-asala mi li ọjọ ipọnju mi. 17 Iwọ, agbara mi, li emi o kọrin si: nitori Ọlọrun li àbo mi, Ọlọrun ánu mi! |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria