O. Daf 54 - Bibeli MimọAdura Ààbò Orin Dafidi, nigbati awọn ara Sifi wá, ti nwọn si sọ fun Saulu pe, Dafidi fi ara rẹ̀ pamọ lọdọ wa. 1 ỌLỌRUN gbà mi nipa orukọ rẹ, si ṣe idajọ mi nipa agbara rẹ. 2 Gbọ́ adura mi, Ọlọrun; fi eti si ọ̀rọ ẹnu mi. 3 Nitoriti awọn alejò dide si mi, awọn aninilara si nwá ọkàn mi: nwọn kò kà Ọlọrun si li oju wọn. 4 Kiyesi i, Ọlọrun li oluranlọwọ mi: Oluwa wà pẹlu awọn ti o gbé ọkàn mi duro. 5 Yio si fi ibi san a fun awọn ọta mi: ke wọn kuro ninu otitọ rẹ. 6 Emi o rubọ atinuwa si ọ: Oluwa, emi o yìn orukọ rẹ; nitoriti o dara. 7 Nitori o ti yọ mi kuro ninu iṣẹ́ gbogbo: oju mi si ri ifẹ rẹ̀ lara awọn ọta mi. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria