Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

O. Daf 52 - Bibeli Mimọ


Ìdájọ́ ati Oore Ọ̀fẹ́ Ọlọrun
Orin Dafidi, nigbati Doegi, ara Edomu, wá, ti o sọ fun Saulu, ti o si wi fun u pe, Dafidi wa si ile Ahimeleki.

1 ẼṢE ti iwọ fi nṣe-fefe ninu ìwa-ìka, iwọ alagbara ọkunrin? ore Ọlọrun duro pẹ titi.

2 Ahọn rẹ ngberò ìwa-ìka; bi abẹ mimú o nṣiṣẹ ẹ̀tan.

3 Iwọ fẹ ibi jù ire lọ; ati eke jù ati sọ ododo lọ.

4 Iwọ fẹ ọ̀rọ ipanirun gbogbo, iwọ ahọn ẹ̀tan.

5 Ọlọrun yio si lù ọ bolẹ lailai, yio si dì ọ mu, yio si ja ọ kuro ni ibujoko rẹ, yio si fà ọ tu kuro lori ilẹ alãye.

6 Olododo yio ri i pẹlu, yio si bẹ̀ru, yio si ma rẹrin rẹ̀ pe,

7 Kiyesi ọkunrin ti kò fi Ọlọrun ṣe agbara rẹ̀; bikoṣe li ọ̀pọlọpọ ọrọ̀ rẹ̀ li o gbẹkẹle, o si mu ara rẹ̀ le ninu ìwa buburu rẹ̀.

8 Ṣugbọn emi dabi igi olifi tutu ni ile Ọlọrun: emi gbẹkẹle ãnu Ọlọrun lai ati lailai.

9 Emi o ma yìn ọ lailai nitoripe iwọ li o ṣe e: emi o si ma duro de orukọ rẹ; nitori ti o dara li oju awọn enia mimọ́ rẹ.

Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

Bible Society of Nigeria
Lean sinn:



Sanasan