O. Daf 51 - Bibeli MimọAdura Ìdáríjì Orin Dafidi, nigbati Natani, woli, tọ̀ ọ wá lẹhin ọ̀ran Batṣeba. 1 ỌLỌRUN, ṣãnu fun mi, gẹgẹ bi iṣeun ifẹ rẹ: gẹgẹ bi ìrọnu ọ̀pọ ãnu rẹ, nù irekọja mi nù kuro. 2 Wẹ̀ mi li awẹmọ́ kuro ninu aiṣedede mi, ki o si wẹ̀ mi nù kuro ninu ẹ̀ṣẹ mi. 3 Nitori ti mo jẹwọ irekọja mi: nigbagbogbo li ẹ̀ṣẹ mi si mbẹ niwaju mi. 4 Iwọ, iwọ nikanṣoṣo ni mo ṣẹ̀ si, ti mo ṣe buburu yi niwaju rẹ: ki a le da ọ lare, nigbati iwọ ba nsọ̀rọ, ki ara rẹ ki o le mọ́, nigbati iwọ ba nṣe idajọ. 5 Kiyesi i, ninu aiṣedede li a gbe bi mi: ati ninu ẹ̀ṣẹ ni iya mi si loyun mi. 6 Kiyesi i, iwọ fẹ otitọ ni inu: ati niha ìkọkọ ni iwọ o mu mi mọ̀ ọgbọ́n. 7 Fi ewe-hissopu fọ̀ mi, emi o si mọ́: wẹ̀ mi, emi o si fún jù ẹ̀gbọn-owu lọ. 8 Mu mi gbọ́ ayọ̀ ati inu didùn; ki awọn egungun ti iwọ ti rún ki o le ma yọ̀. 9 Pa oju rẹ mọ́ kuro lara ẹ̀ṣẹ mi, ki iwọ ki o si nù gbogbo aiṣedede mi nù kuro. 10 Da aiya titun sinu mi, Ọlọrun; ki o si tún ọkàn diduroṣinṣin ṣe sinu mi. 11 Máṣe ṣa mi tì kuro niwaju rẹ; ki o má si ṣe gbà Ẹmi mimọ́ rẹ lọwọ mi. 12 Mu ayọ̀ igbala rẹ pada tọ̀ mi wá; ki o si fi ẹmi omnira rẹ gbé mi duro. 13 Nigbana li emi o ma kọ́ awọn olurekọja li ọ̀na rẹ: awọn ẹlẹṣẹ yio si ma yipada si ọ. 14 Ọlọrun, gbà mi lọwọ ẹbi ẹ̀jẹ, iwọ Ọlọrun igbala mi: ahọn mi yio si ma kọrin ododo rẹ kikan. 15 Oluwa, iwọ ṣi mi li ète; ẹnu mi yio si ma fi iyìn rẹ han: 16 Nitori iwọ kò fẹ ẹbọ, ti emi iba ru u: inu rẹ kò dùn si ọrẹ-ẹbọ sisun. 17 Ẹbọ Ọlọrun ni irobinujẹ ọkàn: irobinujẹ ati irora aiya, Ọlọrun, on ni iwọ kì yio gàn. 18 Ṣe rere ni didùn inu rẹ si Sioni: iwọ mọ odi Jerusalemu. 19 Nigbana ni inu rẹ yio dùn si ẹbọ ododo; pẹlu ọrẹ-ẹbọ sisun ati ọ̀tọtọ ọrẹ-ẹbọ sisun: nigbana ni nwọn o fi akọ-malu rubọ lori pẹpẹ rẹ. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria