O. Daf 49 - Bibeli MimọÌwà Òmùgọ̀ ni Igbẹkẹ le Ọrọ̀ 1 ẸGBỌ́ eyi, gbogbo enia; ẹ fi eti si i, gbogbo ẹnyin araiye: 2 Ati awọn ọmọ-ẹhin ati awọn ẹni-ọlá, awọn ọlọrọ̀ ati awọn talaka pẹlu. 3 Ẹnu mi yio sọ̀rọ ọgbọ́n, ati iṣaro aiya mi yio jẹ oye. 4 Emi o dẹ eti mi silẹ si owe: emi o ṣi ọ̀rọ ìkọkọ mi silẹ loju okùn dùru. 5 Ẽṣe ti emi o fi bẹ̀ru li ọjọ ibi, nigbati ẹ̀ṣẹ awọn ajinilẹsẹ mi yi mi ka. 6 Awọn ti o gbẹkẹle ọrọ̀ wọn, ti nwọn si nṣe ileri li ọ̀pọlọpọ ọrọ̀ wọn; 7 Kò si ẹnikan, bi o ti wù ki o ṣe, ti o le rà arakunrin rẹ̀, bẹ̃ni kò le san owo-irapada fun Ọlọrun nitori rẹ̀. 8 Nitori irapada ọkàn wọn iyebiye ni, o si dẹkun lailai: 9 Nipe ki o fi mã wà lailai, ki o má ṣe ri isa-okú. 10 Nitori o nri pe awọn ọlọgbọ́n nkú, bẹ̃li aṣiwere ati ẹranko enia nṣegbe, nwọn si nfi ọrọ̀ wọn silẹ fun ẹlomiran. 11 Ìro inu wọn ni, ki ile wọn ki o pẹ titi lai, ati ibujoko wọn lati irandiran; nwọn sọ ilẹ wọn ní orukọ ara wọn. 12 Ṣugbọn enia ti o wà ninu ọlá kò duro pẹ: o dabi ẹranko ti o ṣegbé. 13 Ipa ọ̀na wọn yi ni igbẹkẹle wọn: ọ̀rọ wọn si tọ́ li oju awọn ọmọ wọn. 14 Bi agutan li a ntẹ wọn si isa-okú: ikú yio jẹun lara wọn; ẹni diduro-ṣinṣin ni yio jọba wọn li owurọ; ẹwà wọn yio si rẹ̀ kuro, isa-okú si ni ibugbe wọn. 15 Ṣugbọn Ọlọrun ni yio rà ọkàn mi lọwọ isa-okú: nitoripe on o gbà mi. 16 Iwọ máṣe bẹ̀ru, nitori ẹnikan di ọlọrọ̀, nitori iyìn ile rẹ̀ npọ̀ si i. 17 Nitoripe, igbati o ba kú, kì yio kó ohun kan lọ: ogo rẹ̀ kì yio sọkalẹ tọ̀ ọ lẹhin lọ. 18 Nigbati o wà lãye bi o tilẹ nsure fun ọkàn ara rẹ̀: ti awọn enia nyìn ọ, nigbati iwọ nṣe rere fun ara rẹ. 19 Ọkàn yio lọ si ọdọ iran awọn baba rẹ̀; nwọn kì yio ri imọlẹ lailai. 20 Ọkunrin ti o wà ninu ọlá, ti kò moye, o dabi ẹranko ti o ṣegbe. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria