O. Daf 48 - Bibeli MimọOLUWA Tóbi 1 ẸNI-NLA ni Oluwa, ti ã yìn pupọpupọ, ni ilu Ọlọrun wa, li oke ìwa-mimọ́ rẹ̀. 2 Didara ni ipò itẹdo, ayọ̀ gbogbo aiye li òke Sioni, ni iha ariwa, ilu Ọba nla. 3 A mọ̀ Ọlọrun li àbo ninu ãfin rẹ̀. 4 Sa wò o, awọn ọba pejọ pọ̀, nwọn jumọ nkọja lọ. 5 Nwọn ri i, bẹ̃li ẹnu yà wọn; a yọ wọn lẹnu, nwọn yara lọ. 6 Ẹ̀ru bà wọn nibẹ, ati irora bi obinrin ti nrọbi. 7 Iwọ fi ẹfufu ila-õrun fọ́ ọkọ Tarṣiṣi. 8 Bi awa ti gbọ́, bẹ̃li awa ri ni ilu Oluwa awọn ọmọ-ogun, ni ilu Ọlọrun wa: Ọlọrun yio gbé e kalẹ lailai. 9 Awa ti nrò ti iṣeun-ifẹ rẹ, Ọlọrun, li arin tempili rẹ. 10 Ọlọrun, gẹgẹ bi orukọ rẹ, bẹ̃ni iyìn rẹ de opin aiye: ọwọ ọtún rẹ kún fun ododo. 11 Ki òke Sioni ki o yọ̀, ki inu awọn ọmọbinrin Juda ki o dùn, nitori idajọ rẹ. 12 Rìn Sioni kiri, ki o si yi i ka: kà ile-iṣọ rẹ̀. 13 Kiyesi odi rẹ̀, kiyesi ãfin rẹ̀ wọnni; ki ẹnyin le ma wi fun iran atẹle nyin. 14 Nitori Ọlọrun yi Ọlọrun wa ni lai ati lailai: on ni yio ma ṣe amọna wa titi ikú. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria