O. Daf 47 - Bibeli MimọỌba Àwọn Ọba 1 ẸNYIN enia, gbogbo ẹ ṣapẹ; ẹ fi ohùn ayọ̀ hó ihó iṣẹgun si Ọlọrun. 2 Nitori Oluwa Ọga-ogo li ẹ̀ru; on li ọba nla lori ilẹ-aiye gbogbo. 3 On ni yio ṣẹ́ awọn enia labẹ wa, ati awọn orilẹ-ède li atẹlẹsẹ wa. 4 On ni yio yàn ilẹ-ini wa fun wa, ọlá Jakobu, ẹniti o fẹ. 5 Ọlọrun gòke lọ ti on ti ariwo, Oluwa, ti on ti iró ipè. 6 Ẹ kọrin iyìn si Ọlọrun, ẹ kọrin iyìn: ẹ kọrin iyìn si Ọba wa, ẹ kọrin iyìn. 7 Nitori Ọlọrun li Ọba gbogbo aiye: ẹ fi oye kọrin iyìn. 8 Ọlọrun jọba awọn keferi: Ọlọrun joko lori itẹ ìwa-mimọ́ rẹ̀. 9 Awọn alade awọn enia kó ara wọn jọ, ani awọn enia Ọlọrun Abrahamu: nitori asà aiye ti Ọlọrun ni: on li a gbe leke jọjọ. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria