O. Daf 4 - Bibeli MimọIgbẹkẹle OLUWA 1 GBOHÙN mi nigbati mo ba npè, Ọlọrun ododo mi: iwọ li o da mi ni ìde ninu ipọnju; ṣe ojurere fun mi, ki o si gbọ́ adura mi. 2 Ẹnyin ọmọ enia, ẹ o ti sọ ogo mi di itiju pẹ to? ẹnyin o ti fẹ asan pẹ to, ti ẹ o si ma wá eke iṣe? 3 Ṣugbọn ki ẹ mọ̀ pe Oluwa yà ẹni ayanfẹ sọ̀tọ fun ara rẹ̀: Oluwa yio gbọ́ nigbati mo ba kepè e. 4 Ẹ duro ninu ẹ̀ru, ẹ má si ṣe ṣẹ̀; ẹ ba ọkàn nyin sọ̀rọ lori ẹní nyin, ki ẹ si duro jẹ. 5 Ẹ ru ẹbọ ododo, ki ẹ si gbẹkẹ nyin le Oluwa. 6 Ẹni pupọ li o nwipe, Tani yio ṣe rere fun wa? Oluwa, iwọ gbé imọlẹ oju rẹ soke si wa lara. 7 Iwọ ti fi ayọ̀ si mi ni inu, jù igba na lọ ti ọkà wọn ati ọti-waini wọn di pupọ̀. 8 Emi o dubulẹ pẹlu li alafia, emi o si sùn; nitori iwọ, Oluwa, nikanṣoṣo li o nmu mi joko li ailewu. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria