O. Daf 39 - Bibeli MimọÌráhùn Ẹni tí Ìyà ń Jẹ 1 MO ni, emi o ma kiyesi ọ̀na mi, ki emi ki o má fi ahọn mi ṣẹ̀; emi o fi ijanu ko ara mi li ẹnu nigbati enia buburu ba mbẹ niwaju mi. 2 Mo fi idakẹ yadi, mo tilẹ pa ẹnu mi mọ́ kuro li ọ̀rọ rere: ibinujẹ mi si ru soke. 3 Aiya mi gbona ninu mi, nigbati emi nronu, ina ràn: nigbana ni mo fi ahọn mi sọ̀rọ. 4 Oluwa, jẹ ki emi ki o mọ̀ opin mi ati ìwọn ọjọ mi, bi o ti ri; ki emi ki o le mọ̀ ìgbà ti mo ni nihin. 5 Kiyesi i, iwọ ti sọ ọjọ mi dabi ibu atẹlẹwọ; ọjọ ori mi si dabi asan niwaju rẹ: nitõtọ olukuluku enia ninu ijoko rere rẹ̀ asan ni patapata. 6 Nitotọ li àworan asan li enia gbogbo nrìn: nitotọ ni nwọn nyọ ara wọn lẹnu li asan: o nkó ọrọ̀ jọ, kò si mọ̀ ẹniti yio kó wọn lọ. 7 Njẹ nisisiyi, Oluwa kini mo duro de? ireti mi mbẹ li ọdọ rẹ. 8 Gbà mi ninu irekọja mi gbogbo: ki o má si sọ mi di ẹni ẹ̀gan awọn enia buburu. 9 Mo yadi, emi kò ya ẹnu mi; nitoripe iwọ li o ṣe e. 10 Mu ọwọ ìna rẹ kuro li ara mi: emi ṣegbe tan nipa ìja ọwọ rẹ. 11 Nigbati iwọ ba fi ibawi kilọ fun enia nitori ẹ̀ṣẹ, iwọ a ṣe ẹwà rẹ̀ a parun bi kòkoro aṣọ: nitõtọ asan li enia gbogbo. 12 Oluwa, gbọ́ adura mi, ki o si fi eti si ẹkún mi, ki o máṣe pa ẹnu rẹ mọ́ si omije mi: nitori alejo li emi lọdọ rẹ, ati atipo, bi gbogbo awọn baba mi ti ri. 13 Da mi si, ki emi li agbara, ki emi ki o to lọ kuro nihinyi, ati ki emi ki o to ṣe alaisi. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria