O. Daf 36 - Bibeli MimọÌwà ìkà 1 IREKỌJA enia buburu wi ninu ọkàn mi pe; ẹ̀ru Ọlọrun kò si niwaju rẹ̀. 2 Nitoriti o npọ́n ara rẹ̀ li oju ara rẹ̀, titi a o fi ri ẹ̀ṣẹ rẹ̀ lati korira; 3 Ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ li ẹ̀ṣẹ on ẹ̀tan: o ti fi ọgbọ́n ati iṣe rere silẹ, 4 O ngbèro ìwa-ika lori ẹni rẹ̀: o gba ọ̀na ti kò dara; on kò korira ibi. Oore Ọlọrun 5 Oluwa, ãnu rẹ de ọrun; otitọ rẹ de awọsanma. 6 Ododo rẹ dabi awọn òke Ọlọrun; idajọ rẹ dabi ibu nla: Oluwa, iwọ pa enia ati ẹranko mọ́. 7 Ọlọrun, iṣeun-ifẹ rẹ ti dara to! nitori na li awọn ọmọ enia yio ma gbẹkẹ wọn le abẹ ojiji iyẹ-apa rẹ. 8 Ororo ile rẹ yio tẹ wọn lọrùn gidigidi; iwọ o si mu wọn mumi ninu odò ifẹ rẹ. 9 Nitori pe pẹlu rẹ li orisun ìye wà: ninu imọlẹ rẹ li awa o ma ri imọlẹ. 10 Mu iṣeun ifẹ rẹ pẹ si awọn ti o mọ̀ ọ; ati ododo rẹ fun awọn alaiyà diduro. 11 Máṣe jẹ ki ẹsẹ agberaga ki o wá si mi, ki o má si jẹ ki ọwọ enia buburu ki o ṣi mi ni ipò. 12 Nibẹ li awọn oniṣẹ-ẹ̀ṣẹ gbe ṣubu: a rẹ̀ wọn silẹ, nwọn kì yio si le dide. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria