O. Daf 32 - Bibeli MimọÌjẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀ 1 IBUKÚN ni fun awọn ti a dari irekọja wọn jì, ti a bò ẹ̀ṣẹ wọn mọlẹ. 2 Ibukún ni fun ọkunrin na ẹniti Oluwa kò kà ẹ̀ṣẹ si lọrun, ati ninu ẹmi ẹniti ẹ̀tan kò si. 3 Nigbati mo dakẹ, egungun mi di gbigbo nitori igbe mi ni gbogbo ọjọ. 4 Nitori li ọsan ati li oru, ọwọ rẹ wuwo si mi lara: omi ara mi si dabi ọdá-ẹ̀run. 5 Emi jẹwọ ẹ̀ṣẹ mi fun ọ, ati ẹ̀ṣẹ mi li emi kò si fi pamọ́. Emi wipe, emi o jẹwọ ìrekọja mi fun Oluwa: iwọ si dari ẹbi ẹ̀ṣẹ mi jì. 6 Nitori eyi li olukulùku ẹni ìwa-bi-ọlọrun yio ma gbadura si ọ ni igba ti a le ri ọ: nitõtọ ninu iṣan-omi nla, nwọn kì yio sunmọ ọdọ rẹ̀. 7 Iwọ ni ibi ipamọ́ mi: iwọ o pa mi mọ́ kuro ninu iṣẹ́; iwọ o fi orin igbala yi mi ka kiri. 8 Emi o fi ẹsẹ̀ rẹ le ọ̀na, emi o si kọ́ ọ li ọ̀na ti iwọ o rìn: emi o ma fi oju mi tọ́ ọ. 9 Ki ẹnyin ki o máṣe dabi ẹṣin tabi ibaka, ti kò ni iyè ninu: ẹnu ẹniti a kò le ṣe aifi ijanu bọ̀, ki nwọn ki o má ba sunmọ ọ. 10 Ọ̀pọ ikãnu ni yio wà fun enia buburu: ṣugbọn ẹniti o ba gbẹkẹle Oluwa, ãnu ni yio yi i ka kiri. 11 Ki inu nyin ki o dùn niti Oluwa, ẹ si ma yọ̀, ẹnyin olododo; ẹ si ma kọrin fun ayọ̀, gbogbo ẹnyin ti aiya nyin duro ṣinṣin. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria