O. Daf 3 - Bibeli MimọAdura Òwúrọ̀ fun Ìrànlọ́wọ́ Orin Dafidi nigbati o salọ niwaju Absalomu, ọmọ rẹ̀. 1 OLUWA, awọn ti nyọ mi li ẹnu ti npọ̀ to yi! ọ̀pọlọpọ li awọn ti o dide si mi. 2 Ọ̀pọlọpọ li awọn ti o nwi niti ọkàn mi pe, Iranlọwọ kò si fun u nipa ti Ọlọrun. 3 Ṣugbọn iwọ, Oluwa, li asà fun mi; ogo mi; ati olugbe ori mi soke. 4 Emi fi ohùn mi kigbe si Oluwa, o si gbohùn mi lati òke mimọ́ rẹ̀ wá. 5 Emi dubulẹ, mo si sùn; mo si ji; nitori ti Oluwa tì mi lẹhin, 6 Emi kì yio bẹ̀ru ọ̀pọlọpọ enia, ti nwọn rọ̀gba yi mi ka. 7 Dide Oluwa; gbà mi, Ọlọrun mi: nitori iwọ li o lù gbogbo awọn ọta mi li egungun ẹrẹkẹ; iwọ si ká ehin awọn enia buburu. 8 Ti Oluwa ni igbala: ibukún rẹ si mbẹ lara awọn enia rẹ. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria