O. Daf 29 - Bibeli MimọAgbára OLUWA ninu ìjì 1 Ẹ FI fun Oluwa, ẹnyin ọmọ awọn alagbara, ẹ fi ogo ati agbara fun Oluwa. 2 Ẹ fi ogo fun Oluwa, ti o yẹ fun orukọ rẹ̀; ẹ ma sìn Oluwa ninu ẹwà ìwa-mimọ́. 3 Ohùn Oluwa mbẹ lori omi pupọ̀: Ọlọrun ogo nsán ãrá: Oluwa mbẹ lori omi pupọ̀. 4 Ohùn Oluwa li agbara; ohùn Oluwa ni ọlánla. 5 Ohùn Oluwa nfà igi kedari ya; lõtọ, Oluwa nfà igi kedari Lebanoni ya. 6 O mu wọn fò pẹlu bi ọmọ-malu; Lebanoni on Sirioni bi ọmọ agbanrere. 7 Ohùn Oluwa nyà ọwọ iná, 8 Ohùn Oluwa nmì aginju; Oluwa nmì aginju Kadeṣi. 9 Ohùn Oluwa li o nmu abo agbọnrin bi, o si fi igbo didi hàn: ati ninu tempili rẹ̀ li olukuluku nsọ̀rọ ogo rẹ̀. 10 Oluwa joko lori iṣan-omi; nitõtọ, Oluwa joko bi Ọba lailai. 11 Oluwa yio fi agbara fun awọn enia rẹ̀; Oluwa yio fi alafia busi i fun awọn enia rẹ̀. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria