Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

O. Daf 26 - Bibeli Mimọ


Adura Ẹni Rere

1 ṢE idajọ mi, Oluwa; nitori ti mo ti nrìn ninu ìwa titọ mi; emi ti gbẹkẹle Oluwa pẹlu; njẹ ẹsẹ mi kì yio yẹ̀.

2 Wadi mi, Oluwa, ki o si ridi mi; dán inu mi ati ọkàn mi wò.

3 Nitoriti iṣeun-ifẹ rẹ mbẹ niwaju mi: emi si ti nrìn ninu otitọ rẹ.

4 Emi kò ba ẹni asan joko, bẹ̃li emi kì yio ba awọn alayidayida wọle.

5 Emi ti korira ijọ awọn oluṣe-buburu; emi kì yio si ba awọn enia buburu joko.

6 Emi o wẹ̀ ọwọ mi li ailẹṣẹ: bẹ̃li emi o si yi pẹpẹ rẹ ká, Oluwa.

7 Ki emi ki o le fi ohùn ọpẹ rò kalẹ, ti emi o si ma sọ̀rọ gbogbo iṣẹ iyanu rẹ.

8 Oluwa, emi ti nfẹ ibujoko ile rẹ, ibi agọ ọlá rẹ.

9 Máṣe kó ọkàn mi pọ̀ pẹlu awọn ẹlẹṣẹ, tabi ẹmi mi pẹlu awọn enia-ẹ̀jẹ.

10 Li ọwọ ẹniti ìwa-ìka mbẹ, ọwọ ọtún wọn si kún fun abẹtẹlẹ.

11 Ṣugbọn bi o ṣe ti emi, emi o ma rìn ninu ìwatitọ mi: rà mi pada, ki o si ṣãnu fun mi.

12 Ẹsẹ mi duro ni ibi titẹju: ninu awọn ijọ li emi o ma fi ibukún fun Oluwa.

Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

Bible Society of Nigeria
Lean sinn:



Sanasan