O. Daf 22 - Bibeli MimọIgbe Ìrora ati Orin Ìyìn 1 ỌLỌRUN mi, Ọlọrun mi, ẽṣe ti iwọ fi kọ̀ mi silẹ? ti iwọ si jina si igbala mi, ati si ohùn igbe mi? 2 Ọlọrun mi, emi nkigbe li ọsan, ṣugbọn iwọ kò dahùn: ati ni igba oru emi kò dakẹ. 3 Ṣugbọn mimọ́ ni Iwọ, ẹniti o tẹ̀ iyìn Israeli do. 4 Awọn baba wa gbẹkẹle ọ: nwọn gbẹkẹle, iwọ si gbà wọn. 5 Nwọn kigbe pè ọ, a si gbà wọn: nwọn gbẹkẹle ọ, nwọn kò si dãmu. 6 Ṣugbọn kòkoro li emi, kì isi iṣe enia; ẹ̀gan awọn enia, ati ẹlẹya awọn enia. 7 Gbogbo awọn ti o ri mi nfi mi rẹrin ẹlẹya: nwọn nyọ ṣuti ète wọn, nwọn nmì ori pe, 8 Jẹ́ ki o gbẹkẹle Oluwa, on o gbà a là; jẹ ki o gbà a là nitori inu rẹ̀ dùn si i. 9 Ṣugbọn iwọ li ẹniti o mu mi jade lati inu wá: iwọ li o mu mi wà li ailewu, nigbati mo rọ̀ mọ́ ọmu iya mi. 10 Iwọ li a ti fi mi le lọwọ lati inu iya mi wá: iwọ li Ọlọrun mi lati inu iya mi wá. 11 Máṣe jina si mi; nitori ti iyọnu sunmọ etile; nitoriti kò si oluranlọwọ. 12 Akọ-malu pipọ̀ li o yi mi ka: malu Baṣani ti o lagbara rọ̀gba yi mi ka. 13 Nwọn yà ẹnu wọn si mi, bi kiniun ti ndọdẹ kiri, ti nké ramuramu. 14 A tú mi danu bi omi, gbogbo egungun mi si yẹ̀ lori ike: ọkàn mi dabi ida; o yọ́ larin inu mi. 15 Agbara mi di gbigbẹ bi apãdi: ahọn mi si lẹ̀ mọ́ mi li ẹrẹkẹ; iwọ o mu mi dubulẹ ninu erupẹ ikú. 16 Nitoriti awọn aja yi mi ka: ijọ awọn enia buburu ti ká mi mọ́: nwọn lu mi li ọwọ, nwọn si lu mi li ẹsẹ. 17 Mo le kaye gbogbo egungun mi: nwọn tẹjumọ mi; nwọn nwò mi sùn. 18 Nwọn pín aṣọ mi fun ara wọn, nwọn si ṣẹ́ keké le aṣọ-ileke mi. 19 Ṣugbọn iwọ máṣe jina si mi, Oluwa: agbara mi, yara lati ràn mi lọwọ. 20 Gbà ọkàn mi lọwọ idà; ẹni mi kanna lọwọ agbara aja nì. 21 Gbà mi kuro li ẹnu kiniun nì; ki iwọ ki o si gbohùn mi lati ibi iwo awọn agbanrere. 22 Emi o sọ̀rọ orukọ rẹ fun awọn arakunrin mi: li awujọ ijọ li emi o ma yìn ọ, 23 Ẹnyin ti o bẹ̀ru Oluwa, ẹ yìn i; gbogbo ẹnyin iru-ọmọ Jakobu, ẹ yìn i logo: ki ẹ si ma bẹ̀ru rẹ̀ gidigidi, gbogbo ẹnyin irú-ọmọ Israeli. 24 Nitoriti kò kẹgan, bẹ̃ni kò korira ipọnju awọn olupọnju; bẹ̃ni kò pa oju rẹ̀ mọ́ kuro lara rẹ̀; ṣugbọn nigbati o kigbe pè e, o gbọ́. 25 Nipa tirẹ ni iyìn mi yio wà ninu ajọ nla, emi o san ẹjẹ́ mi niwaju awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀. 26 Awọn olupọnju yio jẹ, yio tẹ́ wọn lọrun: awọn ti nwá Oluwa yio yìn i: ọkàn nyin yio wà lailai: 27 Gbogbo opin aiye ni yio ranti, nwọn o si yipada si Oluwa: ati gbogbo ibatan orilẹ-ède ni yio wolẹ-sìn niwaju rẹ̀. 28 Nitori ijọba ni ti Oluwa; on si ni Bãlẹ ninu awọn orilẹ-ède. 29 Gbogbo awọn ti o sanra li aiye yio ma jẹ, nwọn o si ma wolẹ-sìn: gbogbo awọn ti nsọkalẹ lọ sinu erupẹ yio tẹriba niwaju rẹ̀, ati ẹniti kò le pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́ li ãye. 30 Iru kan yio ma sìn i; a o si kà a ni iran kan fun Oluwa. 31 Nwọn o wá, nwọn o si ma sọ̀rọ ododo rẹ̀ fun awọn enia kan ti a o bí, pe, on li o ṣe eyi. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria