O. Daf 16 - Bibeli MimọMo Sá di OLUWA 1 ỌLỌRUN, pa mi mọ́: nitori iwọ ni mo gbẹkẹ mi le. 2 Ọkàn mi, iwọ ti wi fun Oluwa pe, Iwọ li Oluwa mi: emi kò ni ire kan lẹhin rẹ. 3 Si awọn enia mimọ́ ti o wà li aiye, ani si awọn ọlọla, lara ẹniti didùn inu mi gbogbo gbe wà. 4 Ibinujẹ awọn ti nsare tọ̀ ọlọrun miran lẹhin yio pọ̀: ẹbọ ohun mimu ẹ̀jẹ wọn li emi kì yio ta silẹ, bẹ̃li emi kì yio da orukọ wọn li ẹnu mi. 5 Oluwa ni ipin ini mi, ati ti ago mi: iwọ li o mu ìla mi duro. 6 Okùn tita bọ́ sọdọ mi ni ibi daradara; lõtọ, emi ni ogún rere. 7 Emi o fi ibukún fun Oluwa, ẹniti o ti nfun mi ni ìmọ; ọkàn mi pẹlu nkọ́ mi ni wakati oru. 8 Emi ti gbé Oluwa kà iwaju mi nigbagbogbo; nitori o wà li ọwọ ọtún mi, a kì yio ṣi mi ni ipò. 9 Nitorina ni inu mi ṣe dùn, ti ogo mi si nyọ̀; ara mi pẹlu yio simi ni ireti. 10 Nitori iwọ kì yio fi ọkàn mi silẹ ni ipò-okú; bẹ̃ni iwọ kì yio jẹ ki Ẹni Mimọ́ rẹ ki o ri idibajẹ. 11 Iwọ o fi ipa ọ̀na ìye hàn mi; ni iwaju rẹ li ẹkún ayọ̀ wà: li ọwọ ọtún rẹ ni didùn-inu wà lailai. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria