O. Daf 15 - Bibeli MimọÌwà tí Ọlọrun Fẹ́ 1 OLUWA, tani yio ma ṣe atipo ninu agọ rẹ? tani yio ma gbe inu òke mimọ́ rẹ? 2 Ẹniti o nrìn dede, ti nṣiṣẹ ododo, ti o si nsọ otitọ inu rẹ̀. 3 Ẹniti kò fi ahọn rẹ̀ sọ̀rọ ẹni lẹhin, ti kò si ṣe ibi si ẹnikeji rẹ̀, ti kò si gbà ọ̀rọ ẹ̀gan si ẹnikeji rẹ̀. 4 Li oju ẹniti enia-kenia di gigàn; ṣugbọn a ma bu ọla fun awọn ti o bẹ̀ru Oluwa. Ẹniti o bura si ibi ara rẹ̀, ti kò si yipada. 5 Ẹniti kò fi owo rẹ̀ gbà èle, ti kò si gbà owo ẹ̀bẹ si alaiṣẹ. Ẹniti o ba ṣe nkan wọnyi kì yio yẹsẹ lailai. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria