O. Daf 149 - Bibeli MimọOrin Ìyìn sí OLUWA 1 Ẹ fi iyìn fun Oluwa. Ẹ kọ orin titun si Oluwa, ati iyìn rẹ̀ ninu ijọ awọn enia-mimọ́. 2 Jẹ ki Israeli ki o yọ̀ si ẹniti o dá a; jẹ ki awọn ọmọ Sioni ki o kún fun ayọ̀ si Ọba wọn. 3 Jẹ ki nwọn ki o yìn orukọ rẹ̀ ninu ijó: jẹ ki nwọn ki o fi ìlu ati dùru kọrin iyìn si i. 4 Nitori ti Oluwa ṣe inudidùn si awọn enia rẹ̀; yio fi igbala ṣe awọn onirẹlẹ li ẹwà. 5 Jẹ ki awọn enia mimọ́ ki o kún fun ayọ̀ ninu ogo; ki nwọn ki o mã kọrin kikan lori ẹni wọn. 6 Ki iyìn Ọlọrun ki o wà li ẹnu wọn, ati idà oloju meji li ọwọ wọn; 7 Lati san ẹsan lara awọn keferi, ati ijiya lara awọn enia. 8 Lati fi ẹ̀wọn dè awọn ọba wọn, ati lati fi ṣẹkẹṣẹkẹ irin dè awọn ọlọ̀tọ wọn; 9 Lati ṣe idajọ wọn, ti a ti kọwe rẹ̀, ọlá yi ni gbogbo enia mimọ́ rẹ̀ ni. Ẹ fi iyìn fun Oluwa. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria