Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

O. Daf 148 - Bibeli Mimọ


Kí gbogbo ẹ̀dá Yin OLUWA

1 Ẹ fi iyìn fun Oluwa, Ẹ fi iyìn fun Oluwa lati ọrun wá; ẹ fi iyìn fun u ni ibi giga.

2 Ẹ fi iyìn fun u, gbogbo ẹnyin angeli rẹ̀; ẹ fi iyìn fun u, gbogbo ẹnyin ọmọ-ogun rẹ̀.

3 Ẹ fi iyìn fun u, õrun ati oṣupa; ẹ fi iyìn fun u, gbogbo ẹnyin irawọ imọlẹ.

4 Ẹ fi iyìn fun u, ẹnyin ọrun awọn ọrun, ati ẹnyin omi ti mbẹ loke ọrun.

5 Jẹ ki nwọn ki o ma yìn orukọ Oluwa; nitori ti on paṣẹ, a si da wọn.

6 O si fi idi wọn mulẹ lai ati lailai; o si ti ṣe ilana kan ti kì yio kọja.

7 Ẹ yìn Oluwa lati aiye wá, ẹnyin erinmi, ati gbogbo ibu-omi;

8 Iná ati yinyin òjo-didì ati ikũku; ìji mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ;

9 Ẹnyin òke nla, ati gbogbo òke kekere; igi eleso, ati gbogbo igi Kedari;

10 Ẹranko, ati gbogbo ẹran-ọ̀sin; ohun ti nrakò, ati ẹiyẹ́ ti nfò;

11 Awọn ọba aiye, ati gbogbo enia; ọmọ-alade, ati gbogbo onidajọ aiye;

12 Awọn ọdọmọkunrin ati awọn wundia, awọn arugbo enia ati awọn ọmọde;

13 Ki nwọn ki o ma yìn orukọ Oluwa; nitori orukọ rẹ̀ nikan li o li ọlá; ogo rẹ̀ bori aiye on ọrun.

14 O si gbé iwo kan soke fun awọn enia rẹ̀, iyìn fun gbogbo enia mimọ́ rẹ̀; ani awọn ọmọ Israeli, awọn enia ti o sunmọ ọdọ rẹ̀. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.

Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

Bible Society of Nigeria
Lean sinn:



Sanasan