O. Daf 142 - Bibeli MimọAdura Ìrànlọ́wọ́ Orin Dafidi; Adura ti o gbà nigbati o wà ninu iho-okuta. 1 OLUWA ni mo fi ohùn mi kigbe pè; ohùn mi ni mo fi mbẹ̀bẹ mi si Oluwa. 2 Emi tú aroye mi silẹ niwaju rẹ̀; emi fi iṣẹ́ mi hàn niwaju rẹ̀. 3 Nigbati ọkàn mi rẹ̀wẹsi ninu mi, nigbana ni iwọ mọ̀ ipa-ọ̀na mi. Li ọ̀na ti emi nrìn ni nwọn dẹkùn silẹ fun mi nikọ̀kọ. 4 Emi wò ọwọ ọtún, mo si ri pe, kò si ẹnikan ti o mọ̀ mi: àbo dẹti fun mi; kò si ẹniti o nãni ọkàn mi. 5 Oluwa, iwọ ni mo kigbe pè: emi wipe, iwọ li àbo mi ati ipin mi ni ilẹ alãye. 6 Fiyesi igbe mi: nitori ti a rẹ̀ mi silẹ gidigidi: gbà mi lọwọ awọn oninu-nibini mi. Nitori nwọn lagbara ju mi lọ. 7 Mu ọkàn mi jade kuro ninu tubu, ki emi ki o le ma yìn orukọ rẹ; awọn olododo yio yi mi ka kiri; nitori iwọ o fi ọ̀pọlọpọ ba mi ṣe. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria