O. Daf 135 - Bibeli MimọOrin Ìyìn 1 Ẹ yìn Oluwa, Ẹ yìn orukọ Oluwa; ẹ yìn i, ẹnyin iranṣẹ Oluwa. 2 Ẹnyin ti nduro ni ile Oluwa, ninu agbalá ile Ọlọrun wa. 3 Ẹ yìn Oluwa: nitori ti Oluwa ṣeun; ẹ kọrin iyìn si orukọ rẹ̀; ni orin ti o dùn. 4 Nitori ti Oluwa ti yàn Jakobu fun ara rẹ̀; ani Israeli fun iṣura ãyo rẹ̀. 5 Nitori ti emi mọ̀ pe Oluwa tobi, ati pe Oluwa jù gbogbo oriṣa lọ. 6 Ohunkohun ti o wù Oluwa, on ni iṣe li ọrun, ati li aiye, li okun, ati ni ọgbun gbogbo. 7 O mu ikũku gòke lati opin ilẹ wá: o da manamana fun òjo: o nmu afẹfẹ ti inu ile iṣura rẹ̀ wá. 8 Ẹniti o kọlù awọn akọbi Egipti, ati ti enia ati ti ẹranko. 9 Ẹniti o rán àmi ati iṣẹ iyanu si ãrin rẹ, iwọ Egipti, si ara Farao, ati si ara awọn iranṣẹ rẹ̀ gbogbo. 10 Ẹniti o kọlu awọn orilẹ-ède pupọ̀, ti o si pa awọn alagbara ọba. 11 Sihoni, ọba awọn ara Amori, ati Ogu, ọba Baṣani, ati gbogbo ijọba Kenaani: 12 O si fi ilẹ wọn funni ni ini, ini fun Israeli, enia rẹ̀. 13 Oluwa, orukọ rẹ duro lailai; iranti rẹ Oluwa, lati iran-diran. 14 Nitori ti Oluwa yio ṣe idajọ awọn enia rẹ̀, yio si ṣe iyọ́nu si awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, 15 Fadaka on wura li ere awọn keferi, iṣẹ ọwọ enia. 16 Nwọn li ẹnu, ṣugbọn nwọn kò sọ̀rọ; nwọn li oju, ṣugbọn nwọn kò fi riran. 17 Nwọn li eti, ṣugbọn nwọn kò fi gbọran; bẹ̃ni kò si ẽmi kan li ẹnu wọn. 18 Awọn ti o ṣe wọn dabi wọn: bẹ̃ si li olukuluku ẹniti o gbẹkẹle wọn. 19 Ẹnyin arale Israeli, ẹ fi ibukún fun Oluwa, ẹnyin arale Aaroni, ẹ fi ibukún fun Oluwa. 20 Ẹnyin arale Lefi, ẹ fi ibukún fun Oluwa; ẹnyin ti o bẹ̀ru Oluwa, ẹ fi ibukún fun Oluwa. 21 Olubukún li Oluwa, lati Sioni wá, ti ngbe Jerusalemu. Ẹ fi iyìn fun Oluwa. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria