O. Daf 132 - Bibeli MimọMajẹmu Ọlọrun pẹlu Ìdílé Dafidi 1 OLUWA, ranti Dafidi ninu gbogbo ipọnju rẹ̀: 2 Ẹniti o ti bura fun Oluwa, ti o si ṣe ileri ifẹ fun Alagbara Jakobu pe. 3 Nitõtọ, emi kì yio wọ̀ inu agọ ile mi lọ, bẹ̃li emi kì yio gùn ori akete mi; 4 Emi kì yio fi orun fun oju mi, tabi õgbe fun ipenpeju mi, 5 Titi emi o fi ri ibi fun Oluwa, ibujoko fun Alagbara Jakobu. 6 Kiyesi i, awa gburo rẹ̀ ni Efrata: awa ri i ninu oko ẹgàn na. 7 Awa o lọ sinu agọ rẹ̀: awa o ma sìn nibi apoti-itisẹ rẹ̀. 8 Oluwa, dide si ibi isimi rẹ; iwọ, ati apoti agbara rẹ. 9 Ki a fi ododo wọ̀ awọn alufa rẹ: ki awọn enia mimọ rẹ ki o ma hó fun ayọ̀. 10 Nitori ti Dafidi iranṣẹ rẹ, máṣe yi oju ẹni-ororo rẹ pada. 11 Oluwa ti bura nitõtọ fun Dafidi; on kì yio yipada kuro ninu rẹ̀, Ninu iru-ọmọ inu rẹ li emi o gbé kalẹ si ori itẹ́ rẹ. 12 Bi awọn ọmọ rẹ yio ba pa majẹmu mi mọ́ ati ẹri mi ti emi o kọ́ wọn, awọn ọmọ wọn pẹlu yio joko lori itẹ́ rẹ lailai. 13 Nitori ti Oluwa ti yàn Sioni; o ti fẹ ẹ fun ibujoko rẹ̀. 14 Eyi ni ibi isimi mi lailai: nihin li emi o ma gbe; nitori ti mo fẹ ẹ. 15 Emi o bukún onjẹ rẹ̀ pupọ̀-pupọ̀: emi o fi onjẹ tẹ́ awọn talaka rẹ̀ lọrùn. 16 Emi o si fi igbala wọ̀ awọn alufa rẹ̀: awọn enia mimọ́ rẹ̀ yio ma hó fun ayọ̀. 17 Nibẹ li emi o gbe mu iwo Dafidi yọ, emi ti ṣe ilana fitila kan fun ẹni-ororo mi. 18 Awọn ọta rẹ̀ li emi o fi itiju wọ̀: ṣugbọn lara on tikararẹ̀ li ade rẹ̀ yio ma gbilẹ. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria