O. Daf 131 - Bibeli MimọÀṣírí ìfọ̀kànbalẹ̀ 1 OLUWA, aiya mi kò gbega, bẹ̃li oju mi kò gbé soke: bẹ̃li emi kò fi ọwọ mi le ọ̀ran nla, tabi le ohun ti o ga jù mi lọ. 2 Nitõtọ emi mu ọkàn mi simi, mo si mu u dakẹjẹ, bi ọmọ ti a ti ọwọ iya rẹ̀ gbà li ẹnu ọmu: ọkàn mi ri bi ọmọ ti a já li ẹnu ọmu. 3 Israeli, iwọ ni ireti lọdọ Oluwa lati isisiyi lọ ati lailai. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria