Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

O. Daf 127 - Bibeli Mimọ


Abániṣé ni OLUWA

1 BIKOṢEPE Oluwa ba kọ́ ile na, awọn ti nkọ́ ọ nṣiṣẹ lasan: bikoṣepe Oluwa ba pa ilu mọ́, oluṣọ ji lasan.

2 Asan ni fun ẹnyin ti ẹ dide ni kutukutu lati pẹ iṣiwọ, lati jẹ onjẹ lãlã: bẹ̃li o nfi ire fun olufẹ rẹ̀ loju orun.

3 Kiyesi i, awọn ọmọ ni ini Oluwa: ọmọ inu si li ère rẹ̀.

4 Bi ọfà ti ri li ọwọ alagbara, bẹ̃li awọn ọmọ igbà èwe rẹ.

5 Ibukún ni fun ọkunrin na ti apo rẹ̀ kún fun wọn: oju kì yio tì wọn, ṣugbọn nwọn o ṣẹgun awọn ọta li ẹnu ọ̀na.

Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

Bible Society of Nigeria
Lean sinn:



Sanasan