Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

O. Daf 124 - Bibeli Mimọ


Ọlọrun Aláàbò Àwọn Eniyan Rẹ̀

1 IBA máṣe pe Oluwa ti o ti wà fun wa, ki Israeli ki o ma wi nisisiyi;

2 Iba máṣe pe Oluwa ti o ti wà fun wa, nigbati awọn enia duro si wa:

3 Nigbana ni nwọn iba gbé wa mì lãye, nigbati ibinu nwọn ru si wa:

4 Nigbana li omi wọnni iba bò wa mọlẹ, iṣan omi iba ti bori ọkàn wa:

5 Nigbana li agberaga omi iba bori ọkàn wa.

6 Olubukún li Oluwa, ti kò fi wa fun wọn bi ohun ọdẹ fun ehin wọn.

7 Ọkàn wa yọ bi ẹiyẹ jade kuro ninu okùn apẹiyẹ: okùn já, awa si yọ.

8 Iranlọwọ wa mbẹ li orukọ Oluwa, ti o da ọrun on aiye.

Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

Bible Society of Nigeria
Lean sinn:



Sanasan