O. Daf 122 - Bibeli MimọÌyìn Jerusalẹmu 1 INU mi dùn nigbati nwọn wi fun mi pe, Ẹ jẹ ki a lọ si ile Oluwa. 2 Ẹsẹ wa yio duro ni ẹnu-bode rẹ, iwọ Jerusalemu. 3 Jerusalemu, iwọ ti a kọ́ bi ilu ti o fi ara mọra pọ̀ ṣọkan. 4 Nibiti awọn ẹ̀ya ima gòke lọ, awọn ẹ̀ya Oluwa, ẹri fun Israeli, lati ma dupẹ fun orukọ Oluwa. 5 Nitori ibẹ li a gbé itẹ́ idajọ kalẹ, awọn itẹ́ ile Dafidi. 6 Gbadura fun alafia Jerusalemu: awọn ti o fẹ ọ yio ṣe rere. 7 Ki alafia ki o wà ninu odi rẹ, ati ire ninu ãfin rẹ. 8 Nitori awọn arakunrin ati awọn ẹgbẹ mi, emi o wi nisisiyi pe, Ki alafia ki o wà ninu rẹ! 9 Nitori ile Oluwa Ọlọrun wa, emi o ma wá ire rẹ. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria