O. Daf 121 - Bibeli MimọOLUWA Aláàbò Wa 1 EMI o gbé oju mi si ori oke wọnnì, nibo ni iranlọwọ mi yio ti nwa? 2 Iranlọwọ mi yio ti ọwọ Oluwa wá, ti o da ọrun on aiye. 3 On kì yio jẹ́ ki ẹsẹ rẹ ki o yẹ̀; ẹniti npa ọ mọ́ kì yio tõgbe. 4 Kiyesi i, ẹniti npa Israeli mọ́, kì itõgbe, bẹ̃ni kì isùn. 5 Oluwa li olupamọ́ rẹ: Oluwa li ojiji rẹ li ọwọ ọ̀tún rẹ. 6 Orùn kì yio pa ọ nigba ọsan, tabi oṣupa nigba oru. 7 Oluwa yio pa ọ mọ́ kuro ninu ibi gbogbo: yio pa ọkàn rẹ mọ́. 8 Oluwa yio pa alọ ati àbọ rẹ mọ́ lati igba yi lọ, ati titi lailai. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria