O. Daf 120 - Bibeli MimọAdura Ìrànlọ́wọ́ 1 NINU ipọnju mi emi kepè Oluwa, o si da mi lohùn. 2 Oluwa, gbà ọkàn mi, lọwọ ète eke, ati lọwọ ahọn ẹ̀tan? 3 Kini ki a fi fun ọ? tabi kini ki a ṣe si ọ, ahọn ẹ̀tan. 4 Ọfà mimu alagbara, ti on ti ẹyin-iná igi juniperi! 5 Egbe ni fun mi, ti mo ṣe atipo ni Meṣeki, ti mo joko ninu agọ Kedari! 6 O ti pẹ ti ọkàn mi ti ba ẹniti o korira alafia gbe. 7 Alafia ni mo fẹ: ṣugbọn nigbati mo ba sọ̀rọ, ija ni ti wọn. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria