O. Daf 12 - Bibeli MimọAdura Ìrànlọ́wọ́ 1 GBÀ-NI Oluwa; nitori awọn ẹni ìwa-bi-Ọlọrun dasẹ̀; nitori awọn olõtọ dasẹ̀ kuro ninu awọn ọmọ enia. 2 Olukuluku wọn mba ẹnikeji rẹ̀ sọ asan; ète ipọnni ati ọkàn meji ni nwọn fi nsọ. 3 Oluwa yio ké gbogbo ète ipọnni kuro, ati ahọn ti nsọ̀rọ ohun nla. 4 Ti o wipe, Ahọn wa li awa o fi ṣẹgun; ète wa ni ti wa: tani iṣe oluwa wa? 5 Nitori inira awọn talaka, nitori imi-ẹ̀dun awọn alaini, Oluwa wipe, nigbayi li emi o dide; emi o si yọ ọ si ibi ailewu kuro lọwọ ẹniti nfẹ̀ si i. 6 Ọ̀rọ Oluwa, ọ̀rọ funfun ni, bi fadaka ti a yọ́ ni ileru erupẹ, ti a dà ni igba meje. 7 Iwọ o pa wọn mọ́, Oluwa, iwọ o pa olukuluku wọn mọ́ kuro lọwọ iran yi lailai. 8 Awọn enia buburu nrìn ni iha gbogbo, nigbati a ba gbé awọn enia-kenia leke. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria