O. Daf 118 - Bibeli MimọAdura Ọpẹ́ fún Ìṣẹ́gun 1 Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa; nitoriti o ṣeun, nitoriti ãnu rẹ̀ duro lailai. 2 Jẹ ki Israeli ki o wi nisisiyi pe, ãnu rẹ̀ duro lailai. 3 Jẹ ki ara-ile Aaroni ki o wi nisisiyi pe, ãnu rẹ̀ duro lailai. 4 Jẹ ki awọn ti o bẹ̀ru Oluwa ki o wi nisisiyi pe, ãnu rẹ̀ duro lailai. 5 Mo kepè Oluwa ninu ipọnju: Oluwa si da mi lohùn ni ibi àye nla. 6 Oluwa mbẹ fun mi, emi kì yio bẹ̀ru; kili enia le ṣe si mi? 7 Oluwa mbẹ fun mi pẹlu awọn ti nràn mi lọwọ: nitorina li emi o ṣe ri ifẹ mi lori awọn ti o korira mi. 8 O ya lati gbẹkẹle Oluwa, jù ati gbẹkẹle enia lọ. 9 O ya lati gbẹkẹle Oluwa, jù ati gbẹkẹle awọn ọmọ-alade lọ. 10 Gbogbo awọn orilẹ-ède yi mi ka kiri, ṣugbọn li orukọ Oluwa emi o pa wọn run. 11 Nwọn yi mi ka kiri; nitõtọ, nwọn yi mi ka kiri, ṣugbọn li orukọ Oluwa emi o pa wọn run. 12 Nwọn yi mi ka kiri bi oyin; a si pa wọn bi iná ẹgún: li orukọ Oluwa emi o sa pa wọn run. 13 Iwọ tì mi gidigidi ki emi ki o le ṣubu; ṣugbọn Oluwa ràn mi lọwọ. 14 Oluwa li agbara ati orin mi, o si di igbala mi. 15 Ìró ayọ̀ ati ti ìṣẹ́gun mbẹ ninu agọ awọn olododo; ọwọ ọtún Oluwa li a gbega: ọwọ ọtún Oluwa nṣe agbara. 16 Ọwọ ọtún Oluwa li a gbega: ọwọ ọtún Oluwa nṣe agbara. 17 Emi kì yio kú, bikoṣe yiyè, ki emi ki o si ma rohin iṣẹ Oluwa. 18 Oluwa nà mi gidigidi: ṣugbọn kò fi mi fun ikú. 19 Ṣi ilẹkun ẹnu-ọ̀na ododo silẹ fun mi: emi o ba ibẹ wọle, emi o ma yìn Oluwa. 20 Eyi li ẹnu-ọ̀na Oluwa, ti awọn olododo yio ba wọle. 21 Emi o yìn ọ: nitori ti iwọ gbohùn mi, iwọ si di igbala mi. 22 Okuta ti awọn ọ̀mọle kọ̀ silẹ li o di pataki igun ile. 23 Lati ọdọ Oluwa li eyi: o ṣe iyanu li oju wa. 24 Eyi li ọjọ ti Oluwa da: awa o ma yọ̀, inu wa yio si ma dùn ninu rẹ̀. 25 Ṣe igbala nisisiyi, emi mbẹ ọ, Oluwa: Oluwa emi bẹ ọ, rán alafia. 26 Olubukún li ẹniti o mbọ̀ wá li orukọ Oluwa: awa ti fi ibukún fun ọ lati ile Oluwa wá. 27 Ọlọrun li Oluwa, ti o ti fi imọlẹ hàn fun wa: ẹ fi okùn di ẹbọ na mọ́ iwo pẹpẹ na. 28 Iwọ li Ọlọrun mi, emi o si ma yìn ọ, iwọ li Ọlọrun mi, emi o mã gbé ọ ga. 29 Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa; nitori ti o ṣeun: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria