O. Daf 114 - Bibeli MimọOrin Ìrékọjá 1 NIGBATI Israeli jade kuro ni Egipti, ti ara-ile Jakobu kuro ninu àjeji ède enia; 2 Juda di ibi mimọ́ rẹ̀, Israeli di ijọba rẹ̀. 3 Okun ri i, o si sá: Jordani pada sẹhin. 4 Awọn òke nla nfò bi àgbo, ati awọn òke kekèke bi ọdọ-agutan. 5 Kili o ṣe ọ, iwọ okun, ti iwọ fi sá? iwọ Jordani ti iwọ fi pada sẹhin? 6 Ẹnyin òke nla, ti ẹ fi nfò bi àgbo; ati ẹnyin òke kekèke bi ọdọ-agutan? 7 Warìri, iwọ ilẹ, niwaju Oluwa, niwaju Ọlọrun Jakobu. 8 Ẹniti o sọ apata di adagun omi, ati okuta-ibọn di orisun omi. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria