Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

O. Daf 113 - Bibeli Mimọ


Yíyin OLUWA fún Oore Rẹ̀

1 Ẹ ma yìn Oluwa! Ẹ ma yìn, ẹnyin iranṣẹ Oluwa, ẹ ma yìn orukọ Oluwa.

2 Ibukún li orukọ Oluwa lati isisiyi lọ ati si i lailai.

3 Lati ila-õrun titi o fi de ìwọ rẹ̀ orukọ Oluwa ni ki a yìn.

4 Oluwa ga lori gbogbo orilẹ-ède, ogo rẹ̀ si wà lori ọrun.

5 Tali o dabi Oluwa Ọlọrun wa, ti o ngbe ibi giga.

6 Ẹniti o rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ lati wò ohun ti o wà li ọrun ati li aiye!

7 O gbé talaka soke lati inu erupẹ wá, o si gbé olupọnju soke lati ori àtan wá;

8 Ki o le mu u joko pẹlu awọn ọmọ-alade, ani pẹlu awọn ọmọ-alade awọn enia rẹ̀.

9 O mu àgan obinrin gbe inu ile, lati ma ṣe oninu-didùn iya awọn ọmọ. Ẹ ma yìn Oluwa!

Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

Bible Society of Nigeria
Lean sinn:



Sanasan