O. Daf 112 - Bibeli MimọAyọ̀ Ẹni Rere 1 Ẹ ma yìn Oluwa. Ibukún ni fun ẹniti o bẹ̀ru Oluwa, ti inu rẹ̀ dùn jọjọ sí ofin rẹ̀. 2 Iru-ọmọ rẹ̀ yio lagbara li aiye: iran ẹni-diduro-ṣinṣin li a o bukún fun. 3 Ọlà ati ọrọ̀ yio wà ni ile rẹ̀: ododo rẹ̀ si duro lailai. 4 Fun ẹni-diduro-ṣinṣin ni imọlẹ mọ́ li òkunkun: olore-ọfẹ, o si kún fun ãnu, o si ṣe olododo. 5 Enia rere fi oju-rere hàn, a si wínni: imoye ni yio ma fi là ọ̀na iṣẹ rẹ̀. 6 Nitoriti a kì yio yi i nipò pada lailai: olododo yio wà ni iranti titi aiye. 7 Kì yio bẹ̀ru ihin buburu: aiya rẹ̀ ti mu ọ̀na kan, o gbẹkẹle Oluwa. 8 Aiya rẹ̀ ti mulẹ, kì yio bẹ̀ru, titi yio fi ri ifẹ rẹ̀ lori awọn ọta rẹ̀. 9 O ti fún ka, o ti fi fun awọn olupọnju; ododo rẹ̀ duro lailai; ọlá li a o fi gbé iwo rẹ̀ ga. 10 Awọn enia buburu yio ri i, inu wọn o si bajẹ; yio pa ehin rẹ̀ keke, yio si yọ́ danu: ifẹ awọn enia buburu yio ṣegbe. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria