Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

O. Daf 111 - Bibeli Mimọ


Yin OLUWA

1 Ẹ ma yìn Oluwa. Emi o ma yìn Oluwa tinutinu mi, ninu ijọ awọn ẹni diduro-ṣinṣin, ati ni ijọ enia.

2 Iṣẹ Oluwa tobi, iwa-kiri ni fun gbogbo awọn ti o ni ifẹ rẹ̀ ninu.

3 Iṣe rẹ̀ li ọlá on ogo, ododo rẹ̀ si duro lailai.

4 O ṣe iṣẹ iyanu rẹ̀ ni iranti: olore-ọfẹ́ li Oluwa o si kún fun ãnu.

5 O ti fi onjẹ fun awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀: yio ranti majẹmu rẹ̀ lailai.

6 O ti fi iṣẹ agbara rẹ̀ hàn awọn enia rẹ̀, ki o le fun wọn ni ilẹ-ini awọn keferi.

7 Otitọ ati idajọ ni iṣẹ ọwọ rẹ̀; gbogbo ofin rẹ̀ li o daniloju.

8 Nwọn duro lai ati lailai, ninu otitọ ati iduro-ṣinṣin li a ṣe wọn.

9 O rán idande si awọn enia rẹ̀: o ti paṣẹ majẹmu rẹ̀ lailai: mimọ́ ati ọ̀wọ li orukọ rẹ̀.

10 Ibẹru Oluwa ni ipilẹṣẹ ọgbọ́n: oye rere ni gbogbo awọn ti npa ofin rẹ̀ mọ́ ni: iyìn rẹ̀ duro lailai.

Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

Bible Society of Nigeria
Lean sinn:



Sanasan