O. Daf 110 - Bibeli MimọOLUWA ati Àyànfẹ́ Ọba Rẹ̀ 1 OLUWA wi fun Oluwa mi pe, Iwọ joko li ọwọ ọ̀tún mi, titi emi o fi sọ awọn ọta rẹ di apoti-itisẹ rẹ. 2 Oluwa yio nà ọpá agbara rẹ lati Sioni wá: iwọ jọba larin awọn ọta rẹ. 3 Awọn enia rẹ yio jẹ ọrẹ atinuwá li ọjọ ijade-ogun rẹ, ninu ẹwà ìwà-mimọ́: lati inu owurọ wá, iwọ ni ìri ewe rẹ. 4 Oluwa ti bura, kì yio si yi ọkàn pada pe, Iwọ li alufa titi lai nipa ẹsẹ ti Melkisedeki. 5 Oluwa li ọwọ ọtún rẹ ni yio lù awọn ọba jalẹ li ọjọ ibinu rẹ̀. 6 Yio ṣe idajọ lãrin awọn keferi, yio fi okú kún ibi wọnni; yio fọ́ ori lori ilẹ pupọ̀. 7 Yio ma mu ninu odò na li ọ̀na: nitorina ni yio ṣe gbé ori soke. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria