O. Daf 108 - Bibeli MimọAdura Ìrànlọ́wọ́ láti Borí Ọ̀tá 1 OLỌRUN, ọkàn mi ti mura, emi o ma kọrin, emi o si ma fi ogo mi kọrin iyìn. 2 Ji, ohun-elo orin mimọ́ ati dùrù: emi tikarami yio si ji ni kutukutu. 3 Emi o ma yìn ọ, Oluwa, ninu awọn enia: emi o mã kọrin si ọ ninu awọn orilẹ-ède. 4 Nitori ti ãnu rẹ tobi jù ọrun lọ: ati otitọ rẹ titi de awọsanma. 5 Gbé ara rẹ ga, Ọlọrun, lori awọn ọrun: ati ogo rẹ lori gbogbo aiye. 6 Ki a le gbà awọn olufẹ rẹ là: fi ọwọ ọtún rẹ ṣe igbala, ki o si da mi lohùn. 7 Ọlọrun ti sọ̀rọ ninu ìwa-mimọ́ rẹ̀ pe; Emi o yọ̀, emi o pin Ṣekemu, emi o si wọ̀n afonifoji Sukkotu. 8 Ti emi ni Gileadi: ti emi ni Manasse: Efraimu pẹlu li agbara ori mi: Juda li olofin mi: 9 Moabu ni ikoko-iwẹsẹ mi; lori Edomu li emi o bọ́ bata mi si; lori Filistia li emi o ho iho-ayọ̀. 10 Tani yio mu mi wá sinu ilu olodi ni? tani yio sìn mi lọ si Edomu? 11 Iwọ Ọlọrun ha kọ́, ẹniti o ti ṣa wa tì? Ọlọrun, iwọ kì yio si ba awọn ogun wa jade lọ? 12 Fun wa ni iranlọwọ ninu ipọnju: nitori asan ni iranlọwọ enia. 13 Nipasẹ Ọlọrun li awa o ṣe akin; nitori on ni yio tẹ̀ awọn ọta wa mọlẹ. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria