O. Daf 100 - Bibeli MimọOrin Ìyìn 1 Ẹ ho iho ayọ̀ si Oluwa, ẹnyin ilẹ gbogbo. 2 Ẹ fi ayọ̀ sìn Oluwa: ẹ wá ti ẹnyin ti orin si iwaju rẹ̀. 3 Ki ẹnyin ki o mọ̀ pe Oluwa, on li Ọlọrun: on li o dá wa, tirẹ̀ li awa; awa li enia rẹ̀, ati agutan papa rẹ̀. 4 Ẹ lọ si ẹnu ọ̀na rẹ̀ ti ẹnyin ti ọpẹ, ati si agbala rẹ̀ ti ẹnyin ti iyìn: ẹ ma dupẹ fun u, ki ẹ si ma fi ibukún fun orukọ rẹ̀. 5 Nitori ti Oluwa pọ̀ li ore; ãnu rẹ̀ kò nipẹkun; ati otitọ rẹ̀ lati iran-diran. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria