Oniwaasu 10 - Bibeli Mimọ1 OKÚ eṣinṣin o mu ororo-ikunra alapolu bajẹ ki o ma run õrùn buburu: bẹ̃ni wère diẹ wuwo jù ọgbọ́n ati ọlá lọ. 2 Aiya ọlọgbọ́n mbẹ li ọwọ ọtún rẹ̀; ṣugbọn aiya aṣiwère li ọwọ òsi rẹ̀. 3 Ati pẹlu nigbati ẹniti o ṣiwère ba nrìn li ọ̀na, ọgbọ́n rẹ̀ a fò lọ, on a si wi fun olukuluku enia pe aṣiwère li on. 4 Bi ọkàn ijoye ba ru si ọ, máṣe fi ipò rẹ silẹ; nitoripe itũbá ama tù ẹ̀ṣẹ nla. 5 Buburu kan mbẹ ti mo ri labẹ õrùn, bi ìṣina ti o ti ọdọ awọn ijoye wá. 6 A gbe aṣiwère sipò ọlá, awọn ọlọrọ̀ si joko nipò ẹhin. 7 Mo ri awọn ọmọ-ọdọ lori ẹṣin, ati awọn ọmọ-alade nrìn bi ọmọ-ọdọ ni ilẹ. 8 Ẹniti o wà iho ni yio bọ́ sinu rẹ̀; ati ẹniti o si njá ọgbà tútù, ejo yio si bù u ṣán. 9 Ẹnikan ti o nyi okuta ni yio si ti ipa rẹ̀ ni ipalara; ati ẹniti o si nla igi ni yio si wu li ewu. 10 Bi irin ba kújú, ti on kò si pọn oju rẹ̀, njẹ ki on ki o fi agbara si i; ṣugbọn ère ọgbọ́n ni lati fi ọ̀na hàn. 11 Nitõtọ bi ejo ba bu ni ṣán lainitùju; njẹ ère kì yio si fun onitùju. 12 Ọ̀rọ ẹnu ọlọgbọ̀n li ore-ọfẹ; ṣugbọn ète aṣiwère ni yio gbe ara rẹ̀ mì. 13 Ipilẹṣẹ ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ ni wère: ati opin ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ ni isinwin iparun. 14 Aṣiwère pẹlu kún fun ọ̀rọ pupọ: enia kò le sọ ohun ti yio ṣẹ; ati ohun ti yio wà lẹhin rẹ̀, tali o le wi fun u? 15 Lãla aṣiwère da olukuluku wọn li agara, nitoriti kò mọ̀ bi a ti lọ si ilu. 16 Egbé ni fun ọ, iwọ ilẹ, nigbati ọba rẹ ba ṣe ọmọde, ti awọn ọmọ-alade rẹ njẹun ni kutukutu. 17 Ibukún ni fun ọ, iwọ ilẹ, nigbati ọba rẹ ba jẹ ọmọ ọlọlá, ti awọn ọmọ-alade rẹ njẹun li akoko ti o yẹ, fun ilera ti kì si iṣe fun ọti amupara! 18 Nipa ilọra pupọ igi ile a hù; ati nipa ọlẹ ọwọ, ile a si ma jò. 19 Ẹrín li a nsàse fun, ati ọti-waini ni imu inu alãye dùn: owo si ni idahùn ohun gbogbo. 20 Máṣe bu ọba, ki o má ṣe ninu èro rẹ; máṣe bu ọlọrọ̀ ni iyẹwu rẹ; nitoripe ẹiyẹ oju-ọrun yio gbe ohùn na lọ, ohun ti o ni iyẹ-apá yio si sọ ọ̀ran na. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria