Numeri 9 - Bibeli MimọÀjọ Ìrékọjá Keji 1 OLUWA si sọ fun Mose ni ijù Sinai, li oṣù kini ọdún keji ti nwọn ti ilẹ Egipti jade wá, wipe, 2 Ki awọn ọmọ Israeli ki o si ma pa ajọ irekọja mọ́ li akokò rẹ̀. 3 Li ọjọ́ kẹrinla oṣù yi, li aṣalẹ, ni ki ẹnyin ki o ma ṣe e li akokò rẹ̀: gẹgẹ bi aṣẹ rẹ̀ gbogbo, ati gẹgẹ bi ìlana rẹ̀ gbogbo, ni ki ẹnyin ki o pa a mọ́. 4 Mose si sọ fun awọn ọmọ Israeli ki nwọn ki o ma pa ajọ irekọja mọ́: 5 Nwọn si ṣe ajọ irekọja li ọjọ́ kẹrinla, oṣù kini, li aṣalẹ ni ijù Sinai: gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA paṣẹ fun Mose, bẹ̃li awọn ọmọ Israeli ṣe. 6 Awọn ọkunrin kan wà ti nwọn ti ipa okú ọkunrin kan di alaimọ́, nwọn kò si le ṣe ajọ irekọja li ọjọ́ na: nwọn si wá siwaju Mose ati siwaju Aaroni li ọjọ́ na: 7 Awọn ọkunrin na si wi fun u pe, Awa ti ipa okú ọkunrin kan di alaimọ́: nitori kili a o ṣe fàsẹhin ti awa ki o le mú ọrẹ-ẹbọ OLUWA wá li akokò rẹ̀ pẹlu awọn ọmọ Israeli? 8 Mose si wi fun wọn pe, Ẹ duro na; ki emi ki o le gbọ́ aṣẹ ti OLUWA yio pa niti nyin. 9 OLUWA si sọ fun Mose pe, 10 Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Bi ẹnikẹni ninu nyin, tabi ninu iran nyin, ba ti ipa okú di alaimọ́, tabi bi o ba wà li ọ̀na àjo jijìn rére, sibẹ̀ on o pa ajọ irekọja mọ́ fun OLUWA. 11 Li ọjọ́ kẹrinla oṣù keji li aṣalẹ ni ki nwọn ki o pa a mọ́; ki nwọn si fi àkara alaiwu jẹ ẹ ati ewebẹ kikorò: 12 Ki nwọn ki o máṣe kùsilẹ ninu rẹ̀ titi di owurọ̀, bẹ̃ni nwọn kò gbọdọ fọ́ egungun rẹ̀ kan: gẹgẹ bi gbogbo ìlana irekọja ni ki nwọn ki o ṣe e. 13 Ṣugbọn ọkunrin na ti o mọ́ ti kò si sí li ọ̀na àjo, ti o si fàsẹhin lati pa irekọja mọ́, ani ọkàn na li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀: nitoriti kò mú ọrẹ-ẹbọ OLUWA wá li akokò rẹ̀, ọkunrin na yio rù ẹ̀ṣẹ rẹ̀. 14 Bi alejò kan ba si nṣe atipo lọdọ nyin, ti o si nfẹ́ pa irekọja mọ́ fun OLUWA; gẹgẹ bi ìlana irekọja, ati gẹgẹ bi aṣẹ rẹ̀, ni ki o ṣe bẹ̃: ìlana kan ni ki ẹnyin ki o ní, ati fun alejò, ati fun ibilẹ. Ọ̀wọ̀n Iná ( Eks 40:34-38 ) 15 Ati li ọjọ́ ti a gbé agọ́ ró awọsanma si bò agọ́ na, eyinì ni, agọ́ ẹrí: ati li alẹ o si hàn lori agọ́ na bi iná, titi o fi di owurọ̀. 16 Bẹ̃li o si ri nigbagbogbo: awọsanma bò o, ati oye iná li oru. 17 Nigbati awọsanma ba ká soke kuro lori agọ́ na, lẹhin na awọn ọmọ Israeli a si ṣí: nibiti awọsanma ba si duro, nibẹ̀ li awọn ọmọ Israeli idó si. 18 Nipa aṣẹ OLUWA awọn ọmọ Israeli a ṣí, nipa aṣẹ OLUWA nwọn a si dó: ni gbogbo ọjọ́ ti awọsanma ba simi lori agọ́ na, nwọn a dó. 19 Nigbati awọsanma ba si pẹ li ọjọ́ pupọ̀ lori agọ́ na, awọn ọmọ Israeli a si ma ṣe afiyesi aṣẹ OLUWA, nwọn ki si iṣi. 20 Nigba miran awọsanma a wà li ọjọ́ diẹ lori agọ́ na; nigbana gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA nwọn a dó, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA nwọn a si ṣí. 21 Nigba miran awọsanma a duro lati alẹ titi di owurọ̀; nigbati awọsanma si ṣí soke li owurọ̀, nwọn a ṣí: iba ṣe li ọsán tabi li oru, ti awọsanma ba ká soke, nwọn a ṣí. 22 Bi ijọ́ meji ni, tabi oṣù kan, tabi ọdún kan, ti awọsanma ba pẹ lori agọ́ na, ti o simi lé e, awọn ọmọ Israeli a dó, nwọn ki si iṣí: ṣugbọn nigbati o ba ká soke, nwọn a ṣí. 23 Nipa aṣẹ OLUWA nwọn a dó, ati nipa aṣẹ OLUWA nwọn a ṣí: nwọn a ma ṣe afiyesi aṣẹ OLUWA, gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA nipa ọwọ́ Mose. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria