Numeri 5 - Bibeli MimọÀwọn Aláìmọ́ 1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, ki nwọn ki o yọ gbogbo adẹ̀tẹ kuro ni ibudó, ati gbogbo ẹniti o ní isun, ati ẹnikẹni ti o di alaimọ́ nipa okú: 3 Ati ọkunrin ati obinrin ni ki ẹnyin ki o yọ kuro, lẹhin ode ibudó ni ki ẹ fi wọn si; ki nwọn ki o máṣe sọ ibudó wọn di alaimọ́, lãrin eyiti Emi ngbé. 4 Awọn ọmọ Israeli si ṣe bẹ̃, nwọn si yọ wọn sẹhin ibudó: bi OLUWA ti sọ fun Mose, bẹ̃ li awọn ọmọ Israeli ṣe. Ìjìyà fún Ẹ̀ṣẹ̀ 5 OLUWA si sọ fun Mose pe, 6 Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Nigbati ọkunrin kan tabi obinrin kan ba dá ẹ̀ṣẹkẹṣẹ ti enia ida, ti o ṣe irekọja si OLUWA, ti oluwarẹ̀ si jẹ̀bi; 7 Nigbana ni ki nwọn ki o jẹwọ ẹ̀ṣẹ ti nwọn ṣẹ̀: ki o si san ẹsan ẹ̀ṣẹ rẹ̀ li oju-owo, ki o si fi idamarun rẹ̀ lé e, ki o si fi i fun ẹniti on jẹbi rẹ̀. 8 Bi o ba si ṣepe ọkunrin na kò ní ibatan kan lati san ẹsan ẹ̀ṣẹ na fun, ki a san ẹsan na fun OLUWA, ani fun alufa; pẹlu àgbo ètutu, ti a o fi ṣètutu fun u. 9 Ati gbogbo ẹbọ agbesọsoke ohun mimọ́ gbogbo ti awọn ọmọ Israeli, ti nwọn mú tọ̀ alufa wá, yio jẹ́ tirẹ̀. 10 Ati ohun mimọ́ olukuluku, ki o jẹ́ tirẹ̀: ohunkohun ti ẹnikan ba fi fun alufa ki o jẹ́ tirẹ̀. Àwọn Aya Tí Ọkọ Wọn Bá Fura sí 11 OLUWA si sọ fun Mose pe, 12 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Bi aya ọkunrin kan ba yapa, ti o si ṣẹ̀ ẹ, 13 Ti ọkunrin kan si bá a dàpọ, ti o si pamọ́ fun ọkọ rẹ̀, ti o si sin, ti on si di ẹni ibàjẹ́, ti kò si sí ẹlẹri kan si i, ti a kò si mú u mọ ọ, 14 Ti ẹmi owú ba dé si i, ti o si njowú aya rẹ̀, ti obinrin na si di ẹni ibàjẹ́: tabi bi ẹmi owú ba dé si i, ti o si njowú aya rẹ̀, ṣugbọn ti on kò di ẹni ibàjẹ́: 15 Nigbana ni ki ọkunrin na ki o mú aya rẹ́ tọ̀ alufa wá, ki o si mú ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ wá fun u, idamẹwa òṣuwọn efa iyẹfun barle; ki o máṣe dà oróro sori rẹ̀, bẹ̃ni ki o máṣe fi turari sinu rẹ̀; nitoripe ẹbọ ohunjijẹ owú ni, ẹbọ ohunjijẹ iranti ni, ti nmú irekọja wá si iranti. 16 Ki alufa na ki o si mú u sunmọtosi, ki o mu u duro niwaju OLUWA: 17 Ki alufa ki o si bù omi mimọ́ ninu ohun-èlo amọ̀ kan; ati ninu erupẹ ti mbẹ ni ilẹ agọ́ ni ki alufa ki o bù, ki o si fi i sinu omi na: 18 Ki alufa ki o si mu obinrin na duro niwaju OLUWA, ki o si ṣí ibori obinrin na, ki o si fi ẹbọ ohunjijẹ iranti na lé e li ọwọ́, ti iṣe ẹbọ ohunjijẹ owú: ati li ọwọ́ alufa ni omi kikorò ti imú egún wá yio wà. 19 Alufa na yio si mu u bura, yio si wi fun obinrin na pe, Bi ọkunrin kò ba bá ọ dàpọ, bi iwọ kò ba si yàsapakan si ìwa-aimọ́, labẹ ọkọ rẹ, ki iwọ ki o yege omi kikorò yi ti imú egún wá: 20 Ṣugbọn bi iwọ ba yapa, labẹ ọkọ rẹ, ti iwọ si di ẹni ibàjẹ́, ti ọkunrin miran si bá ọ dàpọ laiṣe ọkọ rẹ: 21 Nigbana ni ki alufa ki o mu ki obinrin na fi èpe bura, ki alufa ki o si wi fun obinrin na pe, Ki OLUWA ki o sọ ọ di ẹni egún, ati ẹni ifire ninu awọn enia rẹ, nigbati OLUWA ba mu itan rẹ rà, ti o si mu inu rẹ wú; 22 Ati omi yi ti nmú egún wá ki o wọ̀ inu rẹ lọ, lati mu inu rẹ wú, ati lati mu itan rẹ rà: ki obinrin na ki o si wipe, Amin, amin. 23 Ki alufa ki o si kọ egún yi sinu iwé, ki o si fi omi kikorò na wẹ̀ ẹ nù: 24 Ki o si jẹ ki obinrin na ki o mu omi kikorò na ti imú egún wá: omi na ti imú egún wá yio si wọ̀ inu rẹ̀ lọ, a si di kikorò. 25 Nigbana li alufa yio gbà ẹbọ ohunjijẹ owú na li ọwọ́ obinrin na, yio si fì ẹbọ ohunjijẹ na niwaju OLUWA, yio si ru u lori pẹpẹ: 26 Ki alufa ki o si bù ikunwọ kan ninu ẹbọ ohunjijẹ na, ani iranti rẹ̀, ki o si sun u lori pẹpẹ, lẹhin eyinì ki o jẹ ki obinrin na mu omi na. 27 Nigbati o ba si mu omi na tán, yio si ṣe, bi o ba ṣe ẹni ibàjẹ́, ti o si ṣẹ̀ ọkọ rẹ̀, omi ti imú egún wá yio si wọ̀ inu rẹ̀ lọ, a si di kikorò, inu rẹ̀, a si wú, itan rẹ̀ a si rà: obinrin na a si di ẹni egún lãrin awọn enia rẹ̀. 28 Bi obinrin na kò ba si ṣe ẹni ibàjẹ́, ṣugbọn ti o mọ́; njẹ yio yege, yio si lóyun. 29 Eyi li ofin owú, nigbati obinrin kan ba yapa, labẹ ọkọ rẹ̀, ti o si di ẹni ibàjẹ́; 30 Tabi nigbati ẹmi owú ba dé si ọkọ kan, ti o ba si njowú obinrin rẹ̀; nigbana yio mu obinrin na duro niwaju OLUWA, ki alufa ki o si ṣe gbogbo ofin yi si i. 31 Nigbana li ọkunrin na yio bọ́ kuro ninu aiṣedede, obinrin na yio si rù aiṣedede ara rẹ̀. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria