Matiu 28 - Bibeli MimọAjinde Jesu ( Mak 16:1-10 ; Luk 24:1-12 ; Joh 20:1-10 ) 1 LI opin ọjọ isimi, bi ilẹ ọjọ kini ọ̀sẹ ti bèrẹ si imọ́, Maria Magdalene ati Maria keji wá lati wò ibojì na. 2 Si wò o, ìṣẹlẹ nla ṣẹ̀: nitori angẹli Oluwa ti ọrun sọkalẹ wá, o si yi okuta na kuro, o si joko lé e. 3 Oju rẹ̀ dabi manamana, aṣọ rẹ̀ si fún bi ẹ̀gbọn owu: 4 Nitori ẹ̀ru rẹ̀ awọn oluṣọ warìri, nwọn si dabi okú. 5 Angẹli na si dahùn, o si wi fun awọn obinrin na pe, Ẹ má bẹ̀ru: nitori emi mọ̀ pe ẹnyin nwá Jesu, ti a ti kàn mọ agbelebu. 6 Kò si nihinyi: nitori o ti jinde gẹgẹ bi o ti wi. Wá, ẹ wò ibiti Oluwa ti dubulẹ si. 7 Ẹ si yara lọ isọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, o ti jinde kuro ninu okú; wo o, ó ṣãju nyin lọ si Galili; nibẹ̀ li ẹnyin o gbé ri i: wo o, mo ti sọ fun nyin. 8 Nwọn si fi ibẹru pẹlu ayọ̀ nla yara lọ kuro ni ibojì; nwọn si saré lọ iròhin fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. 9 Bi nwọn si ti nlọ isọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, wo o, Jesu pade wọn, o wipe, Alafia. Nwọn si wá, nwọn si gbá a li ẹsẹ mu, nwọn si tẹriba fun u. 10 Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Ẹ má bẹ̀ru: ẹ lọ isọ fun awọn arakunrin mi pe, ki nwọn ki o lọ si Galili, nibẹ̀ ni nwọn o gbé ri mi. Ìròyìn Àwọn tí Ń Ṣọ́ Ibojì 11 Njẹ bi nwọn ti nlọ, wo o, ninu awọn olusọ wá si ilu, nwọn rohin gbogbo nkan wọnyi ti o ṣe fun awọn olori alufa. 12 Nigbati awọn pẹlu awọn agbàgba pejọ, ti nwọn si gbìmọ, nwọn fi ọ̀pọ owo fun awọn ọmọ-ogun na, 13 Nwọn wi fun wọn pe, Ẹ wipe, Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá li oru, nwọn si ji i gbé lọ nigbati awa sùn. 14 Bi eyi ba de etí Bãlẹ, awa o yi i li ọkàn pada, a o si gbà nyin silẹ. 15 Bẹ̃ni nwọn gbà owo na, nwọn si ṣe gẹgẹ bi a ti kọ́ wọn: ọ̀rọ yi si di rirò kiri lọdọ awọn Ju titi di oni. Jesu Rán Àwọn Ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ Níṣẹ́ ( Mak 16:14-18 ; Luk 24:36-49 ; Joh 20:19-23 ; Iṣe Apo 1:6-8 ) 16 Nigbana li awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mọkanla jade lọ si Galili, si ori òke ti Jesu ti sọ fun wọn. 17 Nigbati nwọn si ri i, nwọn foribalẹ fun u: ṣugbọn awọn miran ṣiyemeji. 18 Jesu si wá, o si sọ fun wọn, wipe, Gbogbo agbara li ọrun ati li aiye li a fifun mi. 19 Nitorina ẹ lọ, ẹ ma kọ́ orilẹ-ède gbogbo, ki ẹ si mã baptisi wọn ni orukọ Baba, ati ni ti Ọmọ, ati ni ti Ẹmí Mimọ́: 20 Ki ẹ mã kọ́ wọn lati mã kiyesi ohun gbogbo, ohunkohun ti mo ti pa li aṣẹ fun nyin: ẹ si kiyesi i, emi wà pẹlu nyin nigbagbogbo, titi o fi de opin aiye. Amin. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria